1
II. A. Ọba 6:17
Bibeli Mimọ
Eliṣa si gbadura, o si wipe, Oluwa, emi bẹ̀ ọ, là a li oju, ki o lè riran. Oluwa si là oju ọdọmọkunrin na; on si riran: si wò o, òke na kún fun ẹṣin ati kẹkẹ́-iná yi Eliṣa ka.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí II. A. Ọba 6:17
2
II. A. Ọba 6:16
On si dahùn wipe, Má bẹ̀ru: nitori awọn ti o wà pẹlu wa, jù awọn ti o wà pẹlu wọn lọ.
Ṣàwárí II. A. Ọba 6:16
3
II. A. Ọba 6:15
Nigbati iranṣẹ enia Ọlọrun na si dide ni kùtukutu ti o si jade lọ, wõ, ogun yi ilu na ka, ati ẹṣin ati kẹkẹ́. Iranṣẹ rẹ̀ si wi fun u pe, Yẽ! baba mi, awa o ti ṣe?
Ṣàwárí II. A. Ọba 6:15
4
II. A. Ọba 6:18
Nigbati nwọn si sọ̀kalẹ tọ̀ ọ wá, Eliṣa gbadura si Oluwa, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, bù ifọju lù awọn enia yi. On si bù ifọju lù wọn gẹgẹ bi ọ̀rọ Eliṣa.
Ṣàwárí II. A. Ọba 6:18
5
II. A. Ọba 6:6
Enia Ọlọrun si wipe, Nibo li o bọ́ si? O si fi ibẹ hàn a. On si ké igi kan, o si sọ́ ọ sinu rẹ̀; irin na si fó soke.
Ṣàwárí II. A. Ọba 6:6
6
II. A. Ọba 6:5
O si ṣe, bi ẹnikan ti nké iti-igi, ãke yọ sinu omi: o si kigbe, o si wipe, Yẽ! oluwa mi, a tọrọ rẹ̀ ni.
Ṣàwárí II. A. Ọba 6:5
7
II. A. Ọba 6:7
Nitorina o wipe, Mu u. On si nà ọwọ rẹ̀, o si mu u.
Ṣàwárí II. A. Ọba 6:7
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò