1
Gẹn 32:28
Bibeli Mimọ
O si wipe, A ki yio pè orukọ rẹ ni Jakobu mọ́, bikoṣe Israeli: nitoripe, iwọ ti ba Ọlọrun ati enia jà, iwọ si bori.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Gẹn 32:28
2
Gẹn 32:26
O si wipe, Jẹ ki emi ki o lọ nitori ti ojúmọ mọ́ tán. On si wipe, Emi ki yio jẹ ki iwọ ki o lọ, bikoṣepe iwọ ba sure fun mi.
Ṣàwárí Gẹn 32:26
3
Gẹn 32:24
O si kù Jakobu nikan; ọkunrin kan si mbá a jijakadi titi o fi di afẹmọ́jumọ.
Ṣàwárí Gẹn 32:24
4
Gẹn 32:30
Jakobu si sọ orukọ ibẹ̀ na ni Penieli: o ni, Nitori ti mo ri Ọlọrun li ojukoju, a si dá ẹmi mi si.
Ṣàwárí Gẹn 32:30
5
Gẹn 32:25
Nigbati o si ri pe on kò le dá a, o fọwọkàn a ni ihò egungun itan rẹ̀; ihò egungun itan Jakobu si yẹ̀ li orike, bi o ti mbá a jijakadi.
Ṣàwárí Gẹn 32:25
6
Gẹn 32:27
O si bi i pe, Orukọ rẹ? On si dahùn pe, Jakobu.
Ṣàwárí Gẹn 32:27
7
Gẹn 32:29
Jakobu si bi i o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, sọ orukọ rẹ fun mi. On si wipe, Ẽṣe ti iwọ fi mbère orukọ mi? o si sure fun u nibẹ̀.
Ṣàwárí Gẹn 32:29
8
Gẹn 32:10
Emi kò yẹ si kikini ninu gbogbo ãnu, ati ninu gbogbo otitọ, ti iwọ fihàn fun ọmọ-ọdọ rẹ, nitori pe, kìki ọpá mi ni mo fi kọja Jordani yi; nisisiyi emi si di ẹgbẹ meji.
Ṣàwárí Gẹn 32:10
9
Gẹn 32:32
Nitori na li awọn ọmọ Israeli ki iṣe ijẹ iṣan ti ifà, ti o wà ni kòto itan, titi o fi di oni-oloni: nitori ti o fọwọkàn kòto egungun itan Jakobu ni iṣan ti ifà.
Ṣàwárí Gẹn 32:32
10
Gẹn 32:9
Jakobu si wipe, Ọlọrun Abrahamu baba mi, ati Ọlọrun Isaaki baba mi, OLUWA ti o wi fun mi pe, pada lọ si ilẹ rẹ, ati sọdọ awọn ara rẹ, emi o si ṣe ọ ni rere
Ṣàwárí Gẹn 32:9
11
Gẹn 32:11
Emi bẹ̀ ọ, gbà mi lọwọ arakunrin mi, lọwọ Esau: nitori ti mo bẹ̀ru rẹ̀, ki o má ba wá lati kọlù mi, ti iya ti ọmọ.
Ṣàwárí Gẹn 32:11
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò