Ki iwọ ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi; Ifibu ni oluwarẹ̀ ti kò ba gbà ọ̀rọ majẹmu yi gbọ́,
Ti mo pa li aṣẹ fun awọn baba nyin, li ọjọ ti mo mu wọn ti ilẹ Egipti jade, lati inu ileru irin wipe, Gbà ohùn mi gbọ́, ki ẹ si ṣe gẹgẹ bi emi ti paṣẹ fun nyin: bẹ̃ni ẹnyin o jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun nyin