1
Mak 8:35
Bibeli Mimọ
Nitori ẹnikẹni ti o ba fẹ gbà ẹmí rẹ̀ là, yio sọ ọ nù: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi ati nitori ihinrere, on na ni yio gbà a là.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Mak 8:35
2
Mak 8:36
Nitoripe ère kini fun enia, bi o jère gbogbo aiye, ti o si sọ ẹmi rẹ̀ nù?
Ṣàwárí Mak 8:36
3
Mak 8:34
O si pè ijọ enia sọdọ rẹ̀, pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o wi fun wọn pe, Bi ẹnikẹni ba fẹ tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ ara rẹ̀, ki o si gbé agbelebu rẹ̀, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin.
Ṣàwárí Mak 8:34
4
Mak 8:37-38
Tabi kili enia iba fi ṣe paṣiparọ ẹmi rẹ̀? Nitori ẹnikẹni ti o ba tiju mi, ati ọ̀rọ mi, ni iran panṣaga ati ẹlẹsẹ yi, on na pẹlu li Ọmọ-enia yio tiju rẹ̀, nigbati o ba de ninu ogo Baba rẹ̀ pẹlu awọn angẹli mimọ́.
Ṣàwárí Mak 8:37-38
5
Mak 8:29
O si bi wọn pe, Ṣugbọn tali ẹnyin nfi mi pè? Peteru si dahùn o si wi fun u pe, Iwọ ni Kristi na.
Ṣàwárí Mak 8:29
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò