Mak 8

8
Jesu Bọ́ Ẹgbaaji (4,000) Eniyan
(Mat 15:32-39)
1LI ọjọ wọnni nigbati ijọ enia pọ̀ gidigidi, ti nwọn ko si li onjẹ, Jesu pè awọn ọmọ-ẹhin rẹ sọdọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe,
2 Ãnu ijọ enia nṣe mi, nitoriti o di ijọ mẹta nisisiyi ti nwọn ti wà lọdọ mi, nwọn kò si li ohun ti nwọn o jẹ:
3 Bi emi ba si rán wọn lọ si ile wọn li ebi, ãrẹ̀ yio mu wọn li ọ̀na: nitori ninu wọn ti ọ̀na jijìn wá.
4Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si da a lohùn wipe, Nibo li a ó gbé ti le fi akara tẹ́ awọn enia wọnyi lọrùn li aginjù yi?
5O si bi wọn lẽre, wipe, Iṣu akara melo li ẹnyin ni? Nwọn si wipe, Meje.
6O si paṣẹ ki awọn enia joko ni ilẹ: o si mu iṣu akara meje na, o dupẹ, o bu u, o si fifun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ki nwọn ki o gbé e kalẹ niwaju wọn; nwọn si gbé e kalẹ niwaju awọn enia.
7Nwọn si li ẹja kekeke diẹ: o si sure, o si ni ki a fi wọn siwaju wọn pẹlu.
8Nwọn si jẹ, nwọn si yó: nwọn si kó ajẹkù ti o kù jọ agbọ̀n meje.
9Awọn ti o jẹ ẹ to ìwọn ẹgbãji enia: o si rán wọn lọ.
10Lojukanna, o si wọ̀ ọkọ̀ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si wá si apa ìha Dalmanuta.
Àwọn Farisi ń fẹ́ Àmì
(Mat 16:1-4)
11Awọn Farisi si jade wá, nwọn bẹrẹ si bi i lẽre, nwọn nfẹ àmi lati ọrun wá lọwọ rẹ̀, nwọn ndán a wò.
12O si kẹdùn gidigidi ninu ọkàn rẹ̀, o si wipe, Ẽṣe ti iran yi fi nwá àmi? lõtọ ni mo wi fun nyin, Ko si àmi ti a o fifun iran yi.
13O si fi wọn silẹ o si tún bọ sinu ọkọ̀ rekọja lọ si apa ekeji.
Ìwúkàrà Àwọn Farisi ati Ti Hẹrọdu
(Mat 16:5-12)
14Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbagbé lati mu akara lọwọ, nwọn kò si ni jù iṣu akara kan ninu ọkọ̀ pẹlu wọn.
15O si kìlọ fun wọn, wipe, Ẹ kiyesara, ki ẹ ma ṣọra nitori iwukara awọn Farisi ati iwukara Herodu.
16Nwọn si mba ara wọn ṣe aroye, wipe, Nitoriti awa kò mu akara lọwọ ni.
17Nigbati Jesu si mọ̀, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi nṣàroye pe ẹnyin ko ni akara lọwọ? ẹnyin ko ti ikiyesi titi di isisiyi, ẹ ko si ti iwoye, ẹnyin si li ọkàn lile titi di isisiyi?
18 Ẹnyin li oju ẹnyin kò si riran? ẹnyin li etí, ẹnyin kò si gbọran? ẹnyin kò si ranti?
19 Nigbati mo bu iṣu akara marun larin ẹgbẹdọgbọn enia, agbọ̀n melo li o kún fun ajẹkù ti ẹnyin kójọ? Nwọn si wi fun u pe, Mejila.
20 Ati nigba iṣu akara meje larin ẹgbaji enia, agbọ̀n melo li o kún fun ajẹkù ti ẹnyin kójọ? Nwọn si wipe, Meje.
21O si wi fun wọn pe, Ẽha ti ṣe ti kò fi yé nyin?
Jesu Wo Afọ́jú kan Sàn ní Bẹtisaida
22O si wá si Betsaida; nwọn si mu afọju kan wá sọdọ rẹ̀, nwọn si bẹ̀ ẹ pe, ki o fi ọwọ́ kàn a.
23O si mu afọju na li ọwọ́, o si fà a jade lọ sẹhin ilu; nigbati o si tutọ́ si i loju, ti o si gbé ọwọ́ rẹ̀ le e, o bi i lẽre bi o ri ohunkohun.
24O si wòke, o si wipe, Mo ri awọn enia dabi igi, nwọn nrìn.
25Lẹhin eyini o si tún fi ọwọ́ kàn a loju, o si mu ki o wòke: o si sàn, o si ri gbogbo enia gbangba.
26O si rán a pada lọ si ile rẹ̀, wipe, Máṣe lọ si ilu, ki o má si sọ ọ fun ẹnikẹni ni ilu.
Peteru Jẹ́wọ́ Ẹni Tí Jesu Í Ṣe
(Mat 16:13-20; Luk 9:18-21)
27Jesu si jade, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọ si awọn ileto Kesarea Filippi: o si bi awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lẽre li ọna, ó wi fun wọn pe, Tali awọn enia nfi mi pè?
28Nwọn si dahùn wipe, Johanu Baptisti: ẹlomiran si wipe Elijah; ṣugbọn awọn ẹlomiran wipe, Ọkan ninu awọn woli.
29O si bi wọn pe, Ṣugbọn tali ẹnyin nfi mi pè? Peteru si dahùn o si wi fun u pe, Iwọ ni Kristi na.
30O si kìlọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ̀rọ on fun ẹnikan.
Jesu Sọtẹ́lẹ̀ nípa Ikú ati Ajinde Rẹ̀
(Mat 16:21-28; Luk 9:22-27)
31O si bẹ̀rẹ si ikọ́ wọn, pe, Ọmọ-enia ko le ṣaima jìya ohun pipọ, a o si kọ̀ ọ lati ọdọ awọn àgbagba ati awọn olori alufa, ati awọn akọwe, a o si pa a, lẹhin ijọ mẹta yio si jinde.
32O si sọ ọ̀rọ na ni gbangba. Peteru si mu u, o bẹ̀rẹ si iba a wi.
33Ṣugbọn o yipada o si wò awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o si ba Peteru wi, o ni, Kuro lẹhin mi, Satani: nitori iwọ ko ro ohun ti Ọlọrun bikoṣe ohun ti enia.
34O si pè ijọ enia sọdọ rẹ̀, pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, o wi fun wọn pe, Bi ẹnikẹni ba fẹ tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ ara rẹ̀, ki o si gbé agbelebu rẹ̀, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin.
35 Nitori ẹnikẹni ti o ba fẹ gbà ẹmí rẹ̀ là, yio sọ ọ nù: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọ ẹmí rẹ̀ nù nitori mi ati nitori ihinrere, on na ni yio gbà a là.
36 Nitoripe ère kini fun enia, bi o jère gbogbo aiye, ti o si sọ ẹmi rẹ̀ nù?
37 Tabi kili enia iba fi ṣe paṣiparọ ẹmi rẹ̀?
38 Nitori ẹnikẹni ti o ba tiju mi, ati ọ̀rọ mi, ni iran panṣaga ati ẹlẹsẹ yi, on na pẹlu li Ọmọ-enia yio tiju rẹ̀, nigbati o ba de ninu ogo Baba rẹ̀ pẹlu awọn angẹli mimọ́.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Mak 8: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀