1
Num 21:8
Bibeli Mimọ
OLUWA si wi fun Mose pe, Rọ ejò amubina kan, ki o si fi i sori ọpá-gigùn kan: yio si ṣe, olukuluku ẹniti ejò ba bùṣan, nigbati o ba wò o, yio yè.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Num 21:8
2
Num 21:9
Mose si rọ ejò idẹ kan, o si fi i sori ọpá-gigùn na: o si ṣe, pe bi ejò kan ba bù enia kan ṣan, nigbati o ba wò ejò idẹ na, on a yè.
Ṣàwárí Num 21:9
3
Num 21:5
Awọn enia na si bá Ọlọrun, ati Mose sọ̀ pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke lati Egipti jade wá lati kú li aginjù? nitoripe àkara kò sí, bẹ̃ni kò sí omi; onjẹ futẹfutẹ yi si sú ọkàn wa.
Ṣàwárí Num 21:5
4
Num 21:6
OLUWA si rán ejò amubina si awọn enia na, nwọn si bù awọn enia na ṣan; ọ̀pọlọpọ ninu Israeli si kú.
Ṣàwárí Num 21:6
5
Num 21:7
Nitorina li awọn enia na ṣe tọ̀ Mose wá, nwọn si wipe, Awa ti ṣẹ̀, nitoriti awa ti bá OLUWA ati iwọ sọ̀; gbadura si OLUWA ki o mú ejò wọnyi kuro lọdọ wa. Mose si gbadura fun awọn enia na.
Ṣàwárí Num 21:7
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò