Num 21
21
Ìṣẹ́gun lórí Àwọn Ará Kenaani
1Ẹni ara Kenaani, ọba Aradi, ti ngbé ìha Gusù, gbọ́ pe Israeli gbà ọ̀na amí yọ; nigbana li o bá Israeli jà, o si mú ninu wọn ni igbekun.
2Israeli si jẹ́ ẹjẹ́ fun OLUWA, wipe, Bi iwọ ba fi awọn enia yi lé mi lọwọ nitõtọ, njẹ emi o run ilu wọn patapata.
3OLUWA si gbọ́ ohùn Israeli, o si fi awọn ara Kenaani tọrẹ, nwọn si run wọn patapata, ati ilu wọn: o si sọ orukọ ibẹ̀ na ni Horma.
Ejò Idẹ
4Nwọn si rìn lati òke Hori lọ li ọ̀na Okun Pupa, lati yi ilẹ Edomu ká: sũru si tán awọn enia na pupọ̀pupọ nitori ọ̀na na.
5Awọn enia na si bá Ọlọrun, ati Mose sọ̀ pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke lati Egipti jade wá lati kú li aginjù? nitoripe àkara kò sí, bẹ̃ni kò sí omi; onjẹ futẹfutẹ yi si sú ọkàn wa.
6OLUWA si rán ejò amubina si awọn enia na, nwọn si bù awọn enia na ṣan; ọ̀pọlọpọ ninu Israeli si kú.
7Nitorina li awọn enia na ṣe tọ̀ Mose wá, nwọn si wipe, Awa ti ṣẹ̀, nitoriti awa ti bá OLUWA ati iwọ sọ̀; gbadura si OLUWA ki o mú ejò wọnyi kuro lọdọ wa. Mose si gbadura fun awọn enia na.
8OLUWA si wi fun Mose pe, Rọ ejò amubina kan, ki o si fi i sori ọpá-gigùn kan: yio si ṣe, olukuluku ẹniti ejò ba bùṣan, nigbati o ba wò o, yio yè.
9Mose si rọ ejò idẹ kan, o si fi i sori ọpá-gigùn na: o si ṣe, pe bi ejò kan ba bù enia kan ṣan, nigbati o ba wò ejò idẹ na, on a yè.
Láti Òkè Hori sí Àfonífojì Moabu
10Awọn ọmọ Israeli si ṣi siwaju, nwọn si dó ni Obotu.
11Nwọn si ṣi lati Obotu lọ, nwọn si dó si Iye-abarimu, li aginjù ti mbẹ niwaju Moabu, ni ìha ìla-õrùn.
12Lati ibẹ̀ lọ nwọn ṣí, nwọn si dó si afonifoji Seredi.
13Lati ibẹ̀ lọ nwọn ṣí, nwọn si dó si ìha keji Arnoni, ti mbẹ li aginjù, ti o ti àgbegbe awọn ọmọ Amori wá: nitoripe Arnoni ni ipinlẹ Moabu, lãrin Moabu ati awọn Amori.
14Nitorina ni a ṣe wi ninu iwé Ogun OLUWA pe, Ohun ti o ṣe li Okun Pupa, ati li odò Arnoni.
15Ati ni iṣàn-odò nì ti o darí si ibujoko Ari, ti o si gbè ipinlẹ Moabu.
16Lati ibẹ̀ nwọn si lọ si Beeri: eyinì ni kanga eyiti OLUWA sọ fun Mose pe, Pe awọn enia jọ, emi o si fun wọn li omi.
17Nigbana ni Israeli kọrin yi pe: Sun jade iwọ kanga; ẹ ma kọrin si i:
18Kanga na, ti awọn olori wà, ti awọn ọlọlá awọn enia si fi ọpá-alade na, ati ọpá wọn wà. Ati lati aginjù na, nwọn lọ si Mattana.
19Ati Mattana nwọn lọ si Nahalieli: ati lati Nahalieli nwọn lọ si Bamotu:
20Ati lati Bamotu li afonifoji nì, ti mbẹ ni ilẹ Moabu, si óke Pisga, ti o si kọjusi aginjù.
Ìṣẹ́gun lórí Ọba Sihoni ati Ọba Ogu
(Deu 2:26—3:11)
21Israeli si rán onṣẹ si Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, wipe,
22Jẹ ki emi là ilẹ rẹ kọja lọ: awa ki yio yà sinu oko, tabi ọgba-àjara; awa ki yio mu ninu omi kanga: ọ̀na opópo ọba li a o gbà, titi awa o fi kọja ipinlẹ rẹ.
23Sihoni kò si jẹ ki Israeli ki o là àgbegbe rẹ̀ kọja: ṣugbọn Sihoni kó gbogbo awọn enia rẹ̀ jọ, nwọn si jade tọ̀ Israeli lọ li aginjù, o si wá si Jahasi, o bá Israeli jà.
24Israeli si fi oju idà kọlù u, o si gbà ilẹ rẹ̀ lati Arnoni lọ dé Jaboku, ani dé ti awọn ọmọ Ammoni; nitoripe ipinlẹ ti awọn ọmọ Ammoni lí agbara.
25Israeli si gbà gbogbo ilunla wọnni: Israeli si joko ninu gbogbo ilunla ti awọn ọmọ Amori, ni Heṣboni, ati ni ilu rẹ̀ gbogbo.
26Nitoripe Heṣboni ni ilunla Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ẹniti o ti bá ọba Moabu atijọ jà, ti o si gbà gbogbo ilẹ rẹ̀ li ọwọ́ rẹ̀, titi dé Arnoni.
27Nitorina awọn ti nkọrin owe a ma wipe, Wá si Heṣboni, jẹ ki a tẹ̀ ilunla Sihoni dó ki a si tun fi idi rẹ̀ mulẹ:
28Nitoriti iná kan ti Heṣboni jade lọ, ọwọ́-iná kan lati ilunla Sihoni: o si run Ari ti Moabu, ati awọn oluwa ibi giga Arnoni.
29Egbé ni fun iwọ, Moabu! Ẹ gbé, ẹnyin enia Kemoṣi: on ti fi awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin bi isansa, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin bi igbekun, fun Sihoni ọba awọn ọmọ Amori.
30Awa tafà si wọn; Heṣboni ṣegbé titi dé Diboni, awa si ti run wọn titi dé Nofa, ti o dé Medeba.
31Bẹ̃li awọn ọmọ Israeli joko ni ilẹ awọn ọmọ Amori.
32Mose si rán enia lọ ṣe amí Jaseri, nwọn si gbà ilu rẹ̀, nwọn si lé awọn ọmọ Amori ti o wà nibẹ̀.
33Nwọn si yipada, nwọn si gòke lọ li ọ̀na Baṣani: Ogu ọba Baṣani si jade tọ̀ wọn lọ, on, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, si ogun ni Edrei.
34OLUWA si wi fun Mose pe, Máṣe bẹ̀ru rẹ̀: nitoripe mo ti fi on lé ọ lọwọ, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, ati ilẹ rẹ̀; ki iwọ ki o si ṣe si i bi iwọ ti ṣe si Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ti ngbé Heṣboni.
35Bẹ̃ni nwọn si kọlù u, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, titi kò fi kù ọkan silẹ fun u lãye: nwọn si gbà ile rẹ̀.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Num 21: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.