1
Owe 29:25
Bibeli Mimọ
Ibẹ̀ru enia ni imu ikẹkùn wá: ṣugbọn ẹnikẹni ti o gbẹkẹ rẹ̀ le Oluwa li a o gbe leke.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Owe 29:25
2
Owe 29:18
Nibiti iran-woli kò si, enia a yapa, ṣugbọn ibukún ni fun ẹniti o pa ofin mọ́.
Ṣàwárí Owe 29:18
3
Owe 29:11
Aṣiwère a sọ gbogbo inu rẹ̀ jade: ṣugbọn ọlọgbọ́n a pa a mọ́ di ìgba ikẹhin.
Ṣàwárí Owe 29:11
4
Owe 29:15
Paṣan ati ibawi funni li ọgbọ́n: ṣugbọn ọmọ ti a ba jọwọ rẹ̀ fun ara rẹ̀, a dojuti iya rẹ̀.
Ṣàwárí Owe 29:15
5
Owe 29:17
Tọ́ ọmọ rẹ, yio si fun ọ ni isimi; yio si fi inu-didùn si ọ li ọkàn.
Ṣàwárí Owe 29:17
6
Owe 29:23
Igberaga enia ni yio rẹ̀ ẹ silẹ: ṣugbọn onirẹlẹ ọkàn ni yio gbà ọlá.
Ṣàwárí Owe 29:23
7
Owe 29:22
Ẹni ibinu ru ìja soke, ati ẹni ikannu pọ̀ ni irekọja.
Ṣàwárí Owe 29:22
8
Owe 29:20
Iwọ ri enia ti o yara li ọ̀rọ rẹ̀? ireti mbẹ fun aṣiwère jù fun u lọ.
Ṣàwárí Owe 29:20
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò