1
Owe 3:5-6
Bibeli Mimọ
Fi gbogbo aiya rẹ gbẹkẹle Oluwa; ma si ṣe tẹ̀ si ìmọ ara rẹ. Mọ̀ ọ ni gbogbo ọ̀na rẹ: on o si ma tọ́ ipa-ọna rẹ.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Owe 3:5-6
2
Owe 3:7
Máṣe ọlọgbọ́n li oju ara rẹ; bẹ̀ru Oluwa, ki o si kuro ninu ibi.
Ṣàwárí Owe 3:7
3
Owe 3:9-10
Fi ohun-ini rẹ bọ̀wọ fun Oluwa, ati lati inu gbogbo akọbi ibisi-oko rẹ: Bẹ̃ni aká rẹ yio kún fun ọ̀pọlọpọ, ati agbá rẹ yio si kún fun ọti-waini titun.
Ṣàwárí Owe 3:9-10
4
Owe 3:3
Máṣe jẹ ki ãnu ati otitọ ki o fi ọ silẹ: so wọn mọ ọrùn rẹ; kọ wọn si walã aiya rẹ
Ṣàwárí Owe 3:3
5
Owe 3:11-12
Ọmọ mi, máṣe kọ̀ ibawi Oluwa; bẹ̃ni ki agara itọ́ni rẹ̀ ki o máṣe dá ọ: Nitoripe ẹniti Oluwa fẹ on ni itọ́, gẹgẹ bi baba ti itọ́ ọmọ ti inu rẹ̀ dùn si.
Ṣàwárí Owe 3:11-12
6
Owe 3:1-2
ỌMỌ mi, máṣe gbagbe ofin mi; si jẹ ki aiya rẹ ki o pa ofin mi mọ́. Nitori ọjọ gigùn, ati ẹmi gigùn, ati alafia ni nwọn o fi kún u fun ọ.
Ṣàwárí Owe 3:1-2
7
Owe 3:13-15
Ibukún ni fun ọkunrin na ti o wá ọgbọ́n ri, ati ọkunrin na ti o gbà oye. Nitori ti òwo rẹ̀ ju òwo fadaka lọ, ère rẹ̀ si jù ti wura daradara lọ. O ṣe iyebiye jù iyùn lọ: ati ohun gbogbo ti iwọ le fẹ, kò si eyi ti a le fi we e.
Ṣàwárí Owe 3:13-15
8
Owe 3:27
Máṣe fawọ ire sẹhin kuro lọdọ ẹniti iṣe tirẹ̀, bi o ba wà li agbara ọwọ rẹ lati ṣe e.
Ṣàwárí Owe 3:27
9
Owe 3:19
Ọgbọ́n li Oluwa fi fi idi aiye sọlẹ, oye li o si fi pese awọn ọrun.
Ṣàwárí Owe 3:19
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò