1
Ifi 7:9
Bibeli Mimọ
Lẹhin na, mo ri, si kiyesi i, ọ̀pọlọpọ enia ti ẹnikẹni kò le kà, lati inu orilẹ-ède gbogbo, ati ẹya, ati enia, ati lati inu ède gbogbo wá, nwọn duro niwaju itẹ́, ati niwaju Ọdọ-Agutan na, a wọ̀ wọn li aṣọ funfun, imọ̀-ọpẹ si mbẹ li ọwọ́ wọn
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Ifi 7:9
2
Ifi 7:10
Nwọn si kigbe li ohùn rara, wipe, Igbala ni ti Ọlọrun wa ti o joko lori itẹ́, ati ti Ọdọ-Agutan.
Ṣàwárí Ifi 7:10
3
Ifi 7:17
Nitori Ọdọ-Agutan ti mbẹ li arin itẹ́ na ni yio mã ṣe oluṣọ-agutan wọn, ti yio si mã ṣe amọna wọn si ibi orisun omi iyè: Ọlọrun yio si nù omije gbogbo nù kuro li oju wọn.
Ṣàwárí Ifi 7:17
4
Ifi 7:15-16
Nitorina ni nwọn ṣe mbẹ niwaju itẹ́ Ọlọrun, ti nwọn si nsìn i li ọsán ati li oru ninu tẹmpili rẹ̀: ẹniti o joko lori itẹ́ na yio si ṣiji bò wọn. Ebi kì yio pa wọn mọ́, bẹ̃li ongbẹ kì yio gbẹ wọn mọ́; bẹ̃li õrùn kì yio pa wọn tabi õrukõru.
Ṣàwárí Ifi 7:15-16
5
Ifi 7:3-4
Wipe, Ẹ máṣe pa aiye, tabi okun, tabi igi lara, titi awa o fi fi èdidi sami si awọn iranṣẹ Ọlọrun wa ni iwaju wọn. Mo si gbọ́ iye awọn ẹniti a fi èdidi sami si: awọn ti a sami si jẹ ọkẹ́ meje o le ẹgbaji lati inu gbogbo ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli wá.
Ṣàwárí Ifi 7:3-4
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò