1
Ifi 8:1
Bibeli Mimọ
NIGBATI o si ṣí èdidi keje, kẹ́kẹ́ pa li ọrun niwọn àbọ wakati kan.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Ifi 8:1
2
Ifi 8:7
Ekini si fun, yinyín ati iná ti o dàpọ̀ pẹlu ẹ̀jẹ si jade, a si dà wọn sori ilẹ aiye: idamẹta ilẹ aiye si jóna, idamẹta awọn igi si jóna, ati gbogbo koriko tutù si jóna.
Ṣàwárí Ifi 8:7
3
Ifi 8:13
Mo si wò, mo si gbọ́ idì kan ti nfò li ãrin ọrun, o nwi li ohùn rara pe, Egbé, egbé, egbé, fun awọn ti ngbe ori ilẹ aiye nitori ohùn ipè iyoku ti awọn angẹli mẹta ti mbọwá fun.
Ṣàwárí Ifi 8:13
4
Ifi 8:8
Angẹli keji si fun, a si wọ́ ohun kan bi òke nla ti njona sọ sinu okun: idamẹta okun si di ẹ̀jẹ
Ṣàwárí Ifi 8:8
5
Ifi 8:10-11
Angẹli kẹta si fun, irawọ̀ nla kan ti njo bi fitila si bọ́ lati ọrun wá, o si bọ sori idamẹta awọn odo ṣiṣàn, ati sori awọn orisun omi; A si npè orukọ irawọ na ni Iwọ idamẹta: awọn omi si di iwọ, ọ̀pọlọpọ enia si ti ipa awọn omi na kú, nitoriti a sọ wọn di kikorò.
Ṣàwárí Ifi 8:10-11
6
Ifi 8:12
Angẹli kẹrin si fun, a si kọlu idamẹta õrùn, ati idamẹta oṣupa, ati idamẹta awọn irawọ, ki idamẹta wọn le ṣõkun, ki ọjọ maṣe mọlẹ fun idamẹta rẹ̀, ati oru bakanna.
Ṣàwárí Ifi 8:12
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò