1
Rom 1:16
Bibeli Mimọ
Nitori emi kò tiju ihinrere Kristi: nitori agbara Ọlọrun ni si igbala fun olukuluku ẹniti o gbagbọ́; fun Ju ṣaju, ati fun Hellene pẹlu.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Rom 1:16
2
Rom 1:17
Nitori ninu rẹ̀ li ododo Ọlọrun hàn lati igbagbọ́ de igbagbọ́: gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ṣugbọn olododo yio wà nipa igbagbọ́.
Ṣàwárí Rom 1:17
3
Rom 1:20
Nitori ohun rẹ̀ ti o farasin lati igba dida aiye a ri wọn gbangba, a nfi òye ohun ti a da mọ̀ ọ, ani agbara ati iwa-Ọlọrun rẹ̀ aiyeraiye, ki nwọn ki o le wà li airiwi
Ṣàwárí Rom 1:20
4
Rom 1:21
Nitori igbati nwọn mọ̀ Ọlọrun, nwọn kò yìn i logo bi Ọlọrun, bẹ̃ni nwọn kò si dupẹ; ṣugbọn èro ọkàn wọn di asán, a si mu ọkàn òmúgọ wọn ṣókunkun.
Ṣàwárí Rom 1:21
5
Rom 1:25
Awọn ẹniti o yi otitọ Ọlọrun pada si eke, nwọn si bọ, nwọn si sìn ẹda jù Ẹlẹda lọ, ẹniti iṣe olubukun titi lai. Amin.
Ṣàwárí Rom 1:25
6
Rom 1:18
Nitori a fi ibinu Ọlọrun hàn lati ọrun wá si gbogbo aiwa-bi-Ọlọrun ati aiṣododo enia, awọn ẹniti o fi aiṣododo tẹ otitọ mọ́lẹ̀
Ṣàwárí Rom 1:18
7
Rom 1:26-28
Nitori eyiyi li Ọlọrun ṣe fi wọn fun ifẹ iwakiwa: nitori awọn obinrin wọn tilẹ yi ilo ẹda pada si eyi ti o lodi si ẹda: Gẹgẹ bẹ̃ li awọn ọkunrin pẹlu, nwọn a mã fi ilò obinrin nipa ti ẹda silẹ, nwọn a mã ni ifẹkufẹ gbigbona si ara wọn; ọkunrin mba ọkunrin ṣe eyi ti kò yẹ, nwọn si njẹ ère ìṣina wọn ninu ara wọn bi o ti yẹ si. Ati gẹgẹ bi nwọn ti kọ̀ lati ni ìro Ọlọrun ni ìmọ wọn, Ọlọrun fi wọn fun iyè rirà lati ṣe ohun ti kò tọ́
Ṣàwárí Rom 1:26-28
8
Rom 1:22-23
Nwọn npè ara wọn li ọlọ́gbọn, nwọn di aṣiwere, Nwọn si pa ogo Ọlọrun ti kì idibajẹ dà, si aworan ere enia ti idibajẹ, ati ti ẹiyẹ, ati ẹranko ẹlẹsẹ mẹrin, ati ohun ti nrakò.
Ṣàwárí Rom 1:22-23
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò