1
Rom 2:3-4
Bibeli Mimọ
Ati iwọ ọkunrin na ti nṣe idajọ awọn ti nṣe irú ohun bawọnni, ti iwọ si nṣe bẹ̃ na, iwọ ro eyi pe iwọ ó yọ ninu idajọ Ọlọrun? Tabi iwọ ngàn ọrọ̀ ore ati ipamọra ati sũru rẹ̀, li aimọ̀ pe ore Ọlọrun li o nfà ọ lọ si ironupiwada?
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Rom 2:3-4
2
Rom 2:1
NITORINA alairiwi ni iwọ ọkunrin na, ẹnikẹni ti o wù ki o jẹ ti ndajọ: nitori ninu ohun ti iwọ nṣe idajọ ẹlomiran, iwọ ndá ara rẹ lẹbi; nitori iwọ ti ndajọ nṣe ohun kanna.
Ṣàwárí Rom 2:1
3
Rom 2:11
Nitori ojuṣaju enia kò si lọdọ Ọlọrun.
Ṣàwárí Rom 2:11
4
Rom 2:13
Nitori kì iṣe awọn olugbọ ofin li alare lọdọ Ọlọrun, ṣugbọn awọn oluṣe ofin li a o dalare.
Ṣàwárí Rom 2:13
5
Rom 2:6
Ẹniti yio san a fun olukuluku gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀
Ṣàwárí Rom 2:6
6
Rom 2:8
Ṣugbọn fun awọn onijà, ti nwọn kò si gbà otitọ gbọ́, ṣugbọn ti nwọn ngbà aiṣododo gbọ́, irunu ati ibinu yio wà.
Ṣàwárí Rom 2:8
7
Rom 2:5
Ṣugbọn gẹgẹ bi lile ati aironupiwada ọkàn rẹ, ni iwọ nfi ibinu ṣura fun ara rẹ de ọjọ ibinu ati ti ifihàn idajọ ododo Ọlọrun
Ṣàwárí Rom 2:5
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò