1
Rom 3:23-24
Bibeli Mimọ
Gbogbo enia li o sá ti ṣẹ̀, ti nwọn si kuna ogo Ọlọrun; Awọn ẹniti a ndalare lọfẹ nipa ore-ọfẹ rẹ̀, nipa idande ti o wà ninu Kristi Jesu
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Rom 3:23-24
2
Rom 3:22
Ani ododo Ọlọrun nipa igbagbọ́ ninu Jesu Kristi, si gbogbo enia, ati lara gbogbo awọn ti o gbagbọ́: nitoriti kò si ìyatọ
Ṣàwárí Rom 3:22
3
Rom 3:25-26
Ẹniti Ọlọrun ti gbe kalẹ lati jẹ ètutu nipa igbagbọ́ ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, lati fi ododo rẹ̀ hàn nitori idariji awọn ẹ̀ṣẹ ti o ti kọja, ninu ipamọra Ọlọrun; Lati fi ododo rẹ̀ hàn ni igba isisiyi: ki o le jẹ olódodo ati oludare ẹniti o gbà Jesu gbọ́.
Ṣàwárí Rom 3:25-26
4
Rom 3:20
Nitoripe nipa iṣẹ ofin, a kì yio dá ẹnikẹni lare niwaju rẹ̀: nitori nipa ofin ni ìmọ ẹ̀ṣẹ ti wá.
Ṣàwárí Rom 3:20
5
Rom 3:10-12
Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Kò si ẹniti iṣe olododo, kò si ẹnikan: Kò si ẹniti oyé yé, kò si ẹniti o nwá Ọlọrun. Gbogbo nwọn li o ti yapa, nwọn jumọ di alailere; kò si ẹniti nṣe rere, kò tilẹ si ẹnikan.
Ṣàwárí Rom 3:10-12
6
Rom 3:28
Nitorina a pari rẹ̀ si pe nipa igbagbọ́ li a nda enia lare laisi iṣẹ ofin.
Ṣàwárí Rom 3:28
7
Rom 3:4
Ki a má ri: k'Ọlọrun jẹ olõtọ, ati olukuluku enia jẹ eke; gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ki a le da ọ lare ninu ọ̀rọ rẹ, ṣugbọn ki iwọ le ṣẹgun nigbati iwọ ba wá si idajọ.
Ṣàwárí Rom 3:4
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò