1
Rom 6:23
Bibeli Mimọ
Nitori ikú li ère ẹ̀ṣẹ; ṣugbọn ẹ̀bun ọfẹ Ọlọrun ni ìye ti kò nipẹkun, ninu Kristi Jesu Oluwa wa.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Rom 6:23
2
Rom 6:14
Nitori ẹ̀ṣẹ kì yio ni ipa lori nyin: nitori ẹnyin kò si labẹ ofin, bikoṣe labẹ ore-ọfẹ.
Ṣàwárí Rom 6:14
3
Rom 6:4
Njẹ a fi baptismu sinu ikú sin wa pọ̀ pẹlu rẹ̀: pe gẹgẹ bi a ti jí Kristi dide kuro ninu okú nipa ogo Baba bẹ̃ni ki awa pẹlu ki o mã rìn li ọtun ìwa.
Ṣàwárí Rom 6:4
4
Rom 6:13
Bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe jọwọ awọn ẹ̀ya ara nyin lọwọ fun ẹ̀ṣẹ bi ohun elo aiṣododo; ṣugbọn ẹ jọwọ ara nyin lọwọ fun Ọlọrun, bi alãye kuro ninu okú, ati awọn ẹ̀ya ara nyin bi ohun elo ododo fun Ọlọrun.
Ṣàwárí Rom 6:13
5
Rom 6:6
Nitori awa mọ eyi pe, a kàn ogbologbo ọkunrin wa mọ agbelebu pẹlu rẹ̀, ki a le pa ara ẹ̀ṣẹ run, ki awa maṣe sìn ẹ̀ṣẹ mọ́.
Ṣàwárí Rom 6:6
6
Rom 6:11
Bẹ̃ni ki ẹnyin pẹlu kà ara nyin bi okú si ẹ̀ṣẹ, ṣugbọn bi alãye si Ọlọrun ninu Kristi Jesu.
Ṣàwárí Rom 6:11
7
Rom 6:1-2
NJẸ awa o ha ti wi? Ki awa ki o ha joko ninu ẹ̀ṣẹ, ki ore-ọfẹ ki o le ma pọ̀ si i? Ki a má ri. Awa ẹniti o ti kú si ẹ̀ṣẹ, awa o ha ṣe wà lãye ninu rẹ̀ mọ́?
Ṣàwárí Rom 6:1-2
8
Rom 6:16
Ẹnyin kò mọ̀ pe, ẹniti ẹnyin ba jọwọ ara nyin lọwọ fun bi ẹrú lati mã gbọ́ tirẹ̀, ẹrú ẹniti ẹnyin ba gbọ tirẹ̀ li ẹnyin iṣe; ibãṣe ti ẹ̀ṣẹ sinu ikú, tabi ti igbọran si ododo?
Ṣàwárí Rom 6:16
9
Rom 6:17-18
Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun pe, bi ẹnyin ti jẹ ẹrú ẹ̀ṣẹ rí, ẹnyin jẹ olugbọran lati ọkàn wá si apẹrẹ ẹkọ ti a fi nyin le lọwọ. Bi a si ti sọ nyin di omnira kuro ninu ẹ̀ṣẹ, ẹnyin di ẹrú ododo.
Ṣàwárí Rom 6:17-18
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò