1
Tit 2:11-12
Bibeli Mimọ
Nitori ore-ọfẹ Ọlọrun ti nmu igbala fun gbogbo enia wá ti farahan, O nkọ́ wa pe, ki a sẹ́ aiwa-bi-Ọlọrun ati ifẹkufẹ aiye, ki a si mã wà li airekọja, li ododo, ati ni ìwa-bi-Ọlọrun ni aiye isisiyi
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Tit 2:11-12
2
Tit 2:13-14
Ki a mã wo ọna fun ireti ti o ni ibukún ati ifarahan ogo Ọlọrun wa ti o tobi, ati ti Olugbala wa Jesu Kristi; Ẹniti o fi ara rẹ̀ fun wa, ki on ki o le rà wa pada kuro ninu ẹ̀ṣẹ gbogbo, ki o si le wẹ awọn enia kan mọ́ fun ara rẹ̀ fun ini on tíkararẹ awọn onitara iṣẹ rere.
Ṣàwárí Tit 2:13-14
3
Tit 2:7-8
Ninu ohun gbogbo mã fi ara rẹ hàn li apẹrẹ iṣẹ rere: ninu ẹkọ́ mã fi aiṣebajẹ hàn, ìwa àgba, Ọ̀rọ ti o yè kõro, ti a kò le da lẹbi; ki oju ki o tì ẹniti o nṣòdi, li aini ohun buburu kan lati wi si wa.
Ṣàwárí Tit 2:7-8
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò