1
1 Ọba 17:14
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Nítorí báyìí ni OLúWA Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Ìkòkò ìyẹ̀fun náà kì yóò ṣófo, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró náà kì yóò gbẹ, títí di ọjọ́ tí OLúWA yóò rọ òjò sí orí ilẹ̀.’ ”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí 1 Ọba 17:14
2
1 Ọba 17:1
Elijah ará Tiṣibi láti Tiṣbi ní Gileadi wí fún Ahabu pé, “Bí OLúWA Ọlọ́run Israẹli ti wà, ẹni tí èmi ń sìn, kì yóò sí ìrì tàbí òjò ní ọdún díẹ̀ tí ń bọ̀ bí kò ṣe nípa ọ̀rọ̀ mi.”
Ṣàwárí 1 Ọba 17:1
3
1 Ọba 17:13
Elijah sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Lọ, kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti wí. Ṣùgbọ́n kọ́kọ́ ṣe àkàrà kékeré kan fún mi nínú rẹ̀ ná, kí o sì mú fún mi wá, lẹ́yìn náà, kí o ṣe tìrẹ àti ti ọmọ rẹ.
Ṣàwárí 1 Ọba 17:13
4
1 Ọba 17:12
Obìnrin opó náà sì dá a lóhùn wí pé, “Bí OLúWA Ọlọ́run rẹ ti wà, èmi kò ní àkàrà: bí kò ṣe ìkúnwọ́ ìyẹ̀fun nínú ìkòkò àti òróró díẹ̀ nínú kólòbó. Èmi ń ṣa igi díẹ̀ jọ láti kó lọ ilé, kí èmi kí ó sì pèsè rẹ̀ fún mi àti fún ọmọ mi, kí àwa lè jẹ ẹ́: kí a sì kú.”
Ṣàwárí 1 Ọba 17:12
5
1 Ọba 17:9
“Lọ nísinsin yìí sí Sarefati ti Sidoni, kí o sì dúró síbẹ̀. Èmi ti pàṣẹ fún obìnrin opó kan níbẹ̀ láti máa bọ́ ọ.”
Ṣàwárí 1 Ọba 17:9
6
1 Ọba 17:16
Nítorí ìkòkò ìyẹ̀fun náà kò ṣófo, kólòbó òróró náà kò gbẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLúWA tí ó ti ipa Elijah sọ.
Ṣàwárí 1 Ọba 17:16
7
1 Ọba 17:15
Ó sì lọ, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Elijah ti sọ fún un. Oúnjẹ sì wà fún Elijah àti obìnrin náà àti ilé rẹ̀ ní ojoojúmọ́.
Ṣàwárí 1 Ọba 17:15
8
1 Ọba 17:10
Bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sí Sarefati. Nígbà tí ó sì dé ibodè ìlú náà, obìnrin opó kan ń ṣa igi jọ níbẹ̀. Ó sì ké sí i, ó sì béèrè pé, “Ǹjẹ́ o lè bu omi díẹ̀ fún mi wá nínú ohun èlò kí èmi kí ó lè mu?”
Ṣàwárí 1 Ọba 17:10
9
1 Ọba 17:4
Ìwọ yóò mu nínú odò náà, mo sì ti pàṣẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò láti máa bọ́ ọ níbẹ̀.”
Ṣàwárí 1 Ọba 17:4
10
1 Ọba 17:11
Bí ó sì ti ń lọ bù ú wá, ó ké sí i pé, “Jọ̀ ọ́, mú òkèlè oúnjẹ díẹ̀ fún mi wá lọ́wọ́ rẹ.”
Ṣàwárí 1 Ọba 17:11
11
1 Ọba 17:6
Àwọn ẹyẹ ìwò sì mú àkàrà àti ẹran wá fún un ní òwúrọ̀, àti àkàrà àti ẹran ní alẹ́, ó sì ń mu nínú odò náà.
Ṣàwárí 1 Ọba 17:6
12
1 Ọba 17:7
Ó sì ṣe lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, odò náà sì gbẹ nítorí kò sí òjò ní ilẹ̀ náà.
Ṣàwárí 1 Ọba 17:7
13
1 Ọba 17:24
Obìnrin náà sì wí fún Elijah pé, “Nísinsin yìí mo mọ̀ pé ènìyàn Ọlọ́run ni ìwọ ń ṣe, àti pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ OLúWA ní ẹnu rẹ.”
Ṣàwárí 1 Ọba 17:24
14
1 Ọba 17:5
Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti sọ fún un. Ó sì lọ sí ẹ̀bá odò Keriti, tí ń bẹ níwájú Jordani, ó sì dúró síbẹ̀.
Ṣàwárí 1 Ọba 17:5
15
1 Ọba 17:22
OLúWA sì gbọ́ igbe Elijah, ẹ̀mí ọmọdé náà sì tún padà tọ̀ ọ́ wá, ó sì sọjí.
Ṣàwárí 1 Ọba 17:22
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò