1
Ìṣe àwọn Aposteli 14:15
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
“Ará, èéṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Ènìyàn bí ẹ̀yin náà ni àwa ń ṣe pẹ̀lú, ti a sì ń wàásù ìhìnrere fún yín, kí ẹ̀yin ba à lè yípadà kúrò nínú ohun asán wọ̀nyí sí Ọlọ́run alààyè, tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Ìṣe àwọn Aposteli 14:15
2
Ìṣe àwọn Aposteli 14:9-10
Ọkùnrin yìí gbọ́ bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀: ẹni, nígbà tí ó tẹjúmọ́ ọn ti ó sì rí i pé, ó ni ìgbàgbọ́ fún ìmúláradá. Ó wí fún un ní ohùn rara pé, “Dìde dúró ṣánṣán lórí ẹsẹ̀ rẹ!” Ó sì ń fò sókè, ó sì ń rìn.
Ṣàwárí Ìṣe àwọn Aposteli 14:9-10
3
Ìṣe àwọn Aposteli 14:23
Nígbà tí wọ́n sì ti yan àwọn alàgbà fún olúkúlùkù ìjọ, tí wọn sì ti fi àwẹ̀ gbàdúrà, wọn fi wọ́n lé Olúwa lọ́wọ, ẹni tí wọn gbàgbọ́.
Ṣàwárí Ìṣe àwọn Aposteli 14:23
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò