1
Esekiẹli 7:19
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
BMYO
“ ‘Wọn yóò dà fàdákà wọn sí ojú pópó, wúrà wọn yóò sì dàbí èérí fàdákà àti wúrà wọn kò ní le gbà wọ́n ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná OLúWA. Wọn kò ní le jẹun tẹ́ ra wọn lọ́rùn tàbí kí wọn kún ikùn wọn pẹ̀lú oúnjẹ nítorí pé ó ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Esekiẹli 7:19
2
Esekiẹli 7:27
Ọba yóò ṣọ̀fọ̀, ọmọ-aládé yóò wà láìní ìrètí, ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yóò wárìrì. Èmi yóò ṣe é fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn, èmi yóò ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìgbékalẹ̀ wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ní OLúWA.’ ”
Ṣàwárí Esekiẹli 7:27
3
Esekiẹli 7:4
Ojú mi kò ní i dá ọ sì, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú; ṣùgbọ́n èmi yóò san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ àti gbogbo ìwà ìríra tó wà láàrín rẹ. Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni OLúWA.’
Ṣàwárí Esekiẹli 7:4
4
Esekiẹli 7:9
Ojú mi kò ní i dá ọ sí, Èmi kò sì ní wò ọ́ pẹ̀lú àánú; èmi yóò san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ àti fún gbogbo ìwà ìríra tí wà láàrín rẹ. “ ‘Nígbà náà ní ẹ o mọ̀ pé Èmi OLúWA lo kọlù yín.
Ṣàwárí Esekiẹli 7:9