1
Gẹnẹsisi 13:15
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Gbogbo ilẹ̀ tí ìwọ ń wò o nì ni èmi ó fi fún ọ àti irú-ọmọ rẹ láéláé.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 13:15
2
Gẹnẹsisi 13:14
OLúWA sì wí fún Abramu lẹ́yìn ìpinyà òun àti Lọti pé, “Gbé ojú rẹ sókè nísinsin yìí, kí o sì wò láti ibi tí o gbé wà a nì lọ sí ìhà àríwá àti sí ìhà gúúsù, sí ìlà-oòrùn àti sí ìwọ̀ rẹ̀.
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 13:14
3
Gẹnẹsisi 13:16
Èmi yóò mú kí irú-ọmọ rẹ kí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó bá ṣe pé ẹnikẹ́ni bá le è ka erùpẹ̀ ilẹ̀, nígbà náà ni yóò tó lè ka irú-ọmọ rẹ.
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 13:16
4
Gẹnẹsisi 13:8
Abramu sì wí fún Lọti pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí èdè-àìyedè kí ó wà láàrín èmi àti ìrẹ, àti láàrín àwọn darandaran wa, nítorí pé ẹbí kan ni àwa ṣe.
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 13:8
5
Gẹnẹsisi 13:18
Nígbà náà ni Abramu kó àgọ́ rẹ̀, ó sì wá, ó sì jókòó ní ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó Mamre, tí ó wà ní Hebroni. Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan sí fún OLúWA.
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 13:18
6
Gẹnẹsisi 13:10
Lọti sì gbójú sókè, ó sì ri wí pé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ni omi rin dáradára bí ọgbà OLúWA, bí ilẹ̀ Ejibiti, ní ọ̀nà Soari. (Èyí ní ìṣáájú kí OLúWA tó pa Sodomu àti Gomorra run).
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 13:10
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò