1
Gẹnẹsisi 22:14
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Abrahamu sì pe orúkọ ibẹ̀ ni, OLúWA yóò pèsè (Jehofah Jire). Bẹ́ẹ̀ ni a sì ń wí títí di òní olónìí pé, “Ní orí òkè OLúWA, ni a ó ti pèsè.”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 22:14
2
Gẹnẹsisi 22:2
Ọlọ́run sì wí pé, “Mú ọmọ rẹ, àní Isaaki ọmọ rẹ kan ṣoṣo nì, tí ìwọ fẹ́ràn, lọ sí ilẹ̀ Moriah, kí o sì fi rú ẹbọ sísun níbẹ̀ lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè tí èmi yóò sọ fún ọ.”
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 22:2
3
Gẹnẹsisi 22:12
Angẹli OLúWA sì wí pé, “Má ṣe fọwọ́ kan ọmọ náà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣe é ni ohun kan. Nísinsin yìí ni mo mọ̀ pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, nítorí pé ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí.”
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 22:12
4
Gẹnẹsisi 22:8
Abrahamu sì dáhùn pé, “Ọmọ mi, Ọlọ́run fúnrarẹ̀ ni yóò pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì jùmọ̀ ń lọ.
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 22:8
5
Gẹnẹsisi 22:17-18
Nítòótọ́, ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i bí i ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí iyanrìn etí Òkun. Irú-ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnu ibodè àwọn ọ̀tá wọn, àti nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni a ó ti bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nítorí tí ìwọ gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu.”
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 22:17-18
6
Gẹnẹsisi 22:1
Nígbà tí ó ṣe, Ọlọ́run dán Abrahamu wò, ó pè é, ó sì wí pé, “Abrahamu.” Abrahamu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 22:1
7
Gẹnẹsisi 22:11
Ṣùgbọ́n angẹli OLúWA ké sí i láti ọ̀run wá wí pé “Abrahamu! Abrahamu!” Abrahamu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 22:11
8
Gẹnẹsisi 22:15-16
Angẹli OLúWA sì tún pe Abrahamu láti ọ̀run wá lẹ́ẹ̀kejì. Ó sì wí pé, OLúWA wí pé, “Mo fi ara mi búra, níwọ̀n bí ìwọ ti ṣe èyí, tí ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 22:15-16
9
Gẹnẹsisi 22:9
Nígbà tí wọn sì dé ibi tí Ọlọ́run sọ fún Abrahamu, ó mọ pẹpẹ kan, ó sì to igi lé e lórí, ó sì di Isaaki ọmọ rẹ̀, ó sì da dùbúlẹ̀ lórí pẹpẹ náà.
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 22:9
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò