1
Gẹnẹsisi 32:28
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí pé, “Orúkọ rẹ kì yóò jẹ́ Jakọbu mọ́ bí kò ṣe Israẹli, nítorí pé ìwọ ti bá Ọlọ́run àti ènìyàn jà, o sì borí.”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 32:28
2
Gẹnẹsisi 32:26
Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń máa lọ, nítorí ojúmọ́ ti mọ́.” Ṣùgbọ́n Jakọbu dá a lóhùn pé, “Èmi kò ní jẹ́ kí o lọ, àyàfi bí o bá súre fún mi.”
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 32:26
3
Gẹnẹsisi 32:24
Ó sì ku Jakọbu nìkan, ọkùnrin kan sì bá a ja ìjàkadì títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́.
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 32:24
4
Gẹnẹsisi 32:30
Jakọbu sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Penieli pé, “Mo rí Ọlọ́run ní ojúkojú, síbẹ̀ a dá ẹ̀mí mi sí.”
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 32:30
5
Gẹnẹsisi 32:25
Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé òun kò le borí Jakọbu, ó fọwọ́ kàn án ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀, egungun náà sì yẹ̀ kúrò lórí ike, bí ó ti ń ja ìjàkadì.
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 32:25
6
Gẹnẹsisi 32:27
Ọkùnrin náà béèrè orúkọ rẹ̀. Ó sì wí fún un pé, “Jakọbu ni òun ń jẹ́.”
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 32:27
7
Gẹnẹsisi 32:29
Jakọbu sì bẹ ọkùnrin náà pé, “Sọ orúkọ rẹ fún mi.” Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà sá à dáhùn pé, “Èéṣe tí o ń béèrè orúkọ mi?” Lẹ́yìn náà ó súre fún Jakọbu níbẹ̀.
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 32:29
8
Gẹnẹsisi 32:10
Èmi kò tilẹ̀ yẹ fún àánú àti òtítọ́ tí o ń fihàn fún ìránṣẹ́ rẹ. Nítorí pé, kìkì ọ̀pá mi ni mo mu kúrò ni ilé kọjá Jordani yìí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, èmi ti di ẹgbẹ́ méjì.
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 32:10
9
Gẹnẹsisi 32:32
Ìdí nìyí tí àwọn ọmọ Israẹli kì í fi í jẹ iṣan tí ó wà ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀ títí di òní olónìí, nítorí níbi iṣan náà ni a ti fọwọ́ kan ibi tí egungun itan Jakọbu ti bẹ̀rẹ̀.
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 32:32
10
Gẹnẹsisi 32:9
Nígbà náà ni Jakọbu gbàdúrà pe, “Ọlọ́run Abrahamu baba mi, àti Ọlọ́run Isaaki baba mi, OLúWA tí ó wí fún mi pé, ‘Padà sí orílẹ̀-èdè rẹ àti sọ́dọ̀ àwọn ìbátan rẹ, Èmi yóò sì ṣe ọ́ ní rere,’
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 32:9
11
Gẹnẹsisi 32:11
Jọ̀wọ́ OLúWA gbà mí lọ́wọ́ Esau arákùnrin mi, nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé yóò wá dojú ìjà kọ mí àti àwọn ìyàwó pẹ̀lú àwọn ọmọ mi.
Ṣàwárí Gẹnẹsisi 32:11
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò