1
Isaiah 25:1
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
OLúWA, ìwọ ni Ọlọ́run mi; Èmi yóò gbé ọ ga èmi ó sì fi ìyìn fún orúkọ rẹ nítorí nínú òtítọ́ aláìlẹ́gbẹ́ o ti ṣe ohun ńlá, àwọn ohun tí o ti gbèrò o rẹ̀ lọ́jọ́ pípẹ́.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Isaiah 25:1
2
Isaiah 25:8
Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé. OLúWA Olódùmarè yóò sì nu gbogbo omijé nù, kúrò ní ojú gbogbo wọn; Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò ní gbogbo ilẹ̀ ayé. OLúWA ni ó ti sọ ọ́.
Ṣàwárí Isaiah 25:8
3
Isaiah 25:9
Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé, “Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa; àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, òun sì gbà wá là. Èyí ni OLúWA, àwa gbẹ́kẹ̀lé e, ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”
Ṣàwárí Isaiah 25:9
4
Isaiah 25:7
Ní orí òkè yìí ni yóò pa aṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn, abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀
Ṣàwárí Isaiah 25:7
5
Isaiah 25:6
Ní orí òkè yìí ni OLúWA àwọn ọmọ-ogun yóò ti pèsè àsè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyàn àpèjẹ ti ọtí wáìnì àtijọ́ ti ẹran tí ó dára jù àti ti ọtí wáìnì tí ó gbámúṣé.
Ṣàwárí Isaiah 25:6
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò