1
Isaiah 38:5
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
“Lọ kí o sì sọ fún Hesekiah pé, ‘Ohun tí OLúWA wí nìyìí, Ọlọ́run Dafidi baba rẹ sọ pé: Èmi ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ; Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ ayé rẹ.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Isaiah 38:5
2
Isaiah 38:3
“Rántí, Ìwọ OLúWA, bí mo ti rìn pẹ̀lú òtítọ́ níwájú rẹ, àti bí mo ti fi ọkàn dídúró ṣinṣin ṣe ohun tí ó dára ní ojú ù rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Hesekiah sì sọkún kíkorò.
Ṣàwárí Isaiah 38:3
3
Isaiah 38:17
Nítòótọ́ fún àlàáfíà ara mi ni, ní ti pé mo ní ìkorò ńlá. Nínú ìfẹ́ rẹ ìwọ pa mí mọ́, kúrò nínú ọ̀gbun ìparun; ìwọ sì ti fi gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.
Ṣàwárí Isaiah 38:17
4
Isaiah 38:1
Ní ọjọ́ náà ni Hesekiah ṣe àìsàn dé ojú ikú. Wòlíì Isaiah ọmọ Amosi sì lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Ohun tí OLúWA wí nìyìí: Palẹ̀ ilé è rẹ mọ́, bí ó ti yẹ nítorí pé ìwọ yóò kú; ìwọ kì yóò dìde àìsàn yìí.”
Ṣàwárí Isaiah 38:1
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò