1
Numeri 13:30
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Kalebu sì pa àwọn ènìyàn náà lẹ́nu mọ́ níwájú Mose, ó wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á gòkè lọ lẹ́ẹ̀kan náà láti lọ gba ilẹ̀ náà, nítorí pé àwa le è gbà á.”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Numeri 13:30
2
Numeri 13:33
A sì tún rí àwọn òmíràn (irú àwọn ọmọ Anaki) àwa sì rí bí i kòkòrò tata ní ojú ara wa, bẹ́ẹ̀ ni àwa náà sì rí ní ojú wọn.”
Ṣàwárí Numeri 13:33
3
Numeri 13:31
Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin tí wọ́n jọ gòkè lọ yẹ ilẹ̀ wò sọ pé, “Àwa kò le gòkè lọ bá àwọn ènìyàn wọ̀nyí nítorí pé wọ́n lágbára jù wá lọ.”
Ṣàwárí Numeri 13:31
4
Numeri 13:32
Báyìí ni wọ́n ṣe mú ìròyìn búburú ti ilẹ̀ náà, tí wọ́n lọ yọ́wò wá fún àwọn ọmọ Israẹli. Wọ́n wí pé, “Ilẹ̀ tí a lọ yẹ̀ wò jẹ́ ilẹ̀ tí ń run àwọn olùgbé ibẹ̀. Gbogbo àwọn ènìyàn tí a rí níbẹ̀ jẹ́ ènìyàn tó fìrìgbọ̀n tó sì síngbọnlẹ̀.
Ṣàwárí Numeri 13:32
5
Numeri 13:27
Wọ́n sì fún Mose ní ìròyìn báyìí: “A lọ sí ilẹ̀ ibi tí o rán wa, lóòtítọ́ ló sì ń sàn fún wàrà àti fún oyin! Èso ibẹ̀ nìyìí.
Ṣàwárí Numeri 13:27
6
Numeri 13:28
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tó ń gbé níbẹ̀ lágbára, àwọn ìlú náà jẹ́ ìlú olódi bẹ́ẹ̀ ni ó sì tóbi púpọ̀. A tilẹ̀ rí àwọn irú-ọmọ Anaki níbẹ̀.
Ṣàwárí Numeri 13:28
7
Numeri 13:29
Àwọn Amaleki ń gbé ní ìhà gúúsù; àwọn ará Hiti, àwọn ará Jebusi àti àwọn ará Amori ni wọ́n ń gbé ní orí òkè ilẹ̀ náà, àwọn ará Kenaani sì ń gbé ẹ̀bá Òkun àti ní etí bèbè Jordani.”
Ṣàwárí Numeri 13:29
8
Numeri 13:26
Wọ́n padà wá bá Mose àti Aaroni àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní ijù Kadeṣi Parani. Wọ́n mú ìròyìn wá fún wọn àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn, wọ́n fi èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n.
Ṣàwárí Numeri 13:26
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò