1
Òwe 11:25
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Ẹni tí ń ṣoore yóò máa gbèrú sí i; ẹni tí ó tu ẹlòmíràn lára yóò ní ìtura.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Òwe 11:25
2
Òwe 11:24
Ènìyàn kan ń fún ni lọ́fẹ̀ẹ́, síbẹ̀ ó ń ní sí i; òmíràn ń háwọ́ ju bí ó ti yẹ ṣùgbọ́n ó di aláìní.
Ṣàwárí Òwe 11:24
3
Òwe 11:2
Nígbà tí ìgbéraga bá dé, nígbà náà ni ìdójútì dé ṣùgbọ́n, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ni ọgbọ́n ń wá.
Ṣàwárí Òwe 11:2
4
Òwe 11:14
Nítorí àìní ìtọ́sọ́nà orílẹ̀-èdè ṣubú ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn ìṣẹ́gun dájú.
Ṣàwárí Òwe 11:14
5
Òwe 11:30
Èso òdodo ni igi ìyè ẹni tí ó sì jèrè ọkàn jẹ́ ọlọ́gbọ́n.
Ṣàwárí Òwe 11:30
6
Òwe 11:13
Olófòófó tú àṣírí ìkọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a pa àṣírí mọ́.
Ṣàwárí Òwe 11:13
7
Òwe 11:17
Ènìyàn rere ń ṣe ara rẹ̀ lóore ṣùgbọ́n ènìyàn ìkà ń mú ìyọnu wá sórí ara rẹ̀.
Ṣàwárí Òwe 11:17
8
Òwe 11:28
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóò ṣubú; ṣùgbọ́n olódodo yóò gbilẹ̀ bí i koríko tútù.
Ṣàwárí Òwe 11:28
9
Òwe 11:4
Ọ̀rọ̀ kò níláárí ní ọjọ́ ìbínú ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú.
Ṣàwárí Òwe 11:4
10
Òwe 11:3
Òtítọ́ inú ẹni dídúró ṣinṣin ń ṣe amọ̀nà rẹ̀ ṣùgbọ́n aláìṣòótọ́ yóò parun nípasẹ̀ àìṣòótọ́ wọn.
Ṣàwárí Òwe 11:3
11
Òwe 11:22
Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀ ni arẹwà obìnrin tí kò lọ́gbọ́n.
Ṣàwárí Òwe 11:22
12
Òwe 11:1
OLúWA kórìíra òṣùwọ̀n èké, ṣùgbọ́n òṣùwọ̀n òtítọ́ jẹ́ inú dídùn un rẹ̀.
Ṣàwárí Òwe 11:1
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò