1
Òwe 22:6
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀: nígbà tí ó bá dàgbà, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Òwe 22:6
2
Òwe 22:4
Èrè ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù OLúWA ni ọrọ̀ ọlá, àti ìyè.
Ṣàwárí Òwe 22:4
3
Òwe 22:1
Yíyan orúkọ rere sàn ju púpọ̀ ọrọ̀ lọ, àti ojúrere dára ju fàdákà àti wúrà lọ.
Ṣàwárí Òwe 22:1
4
Òwe 22:24
Má ṣe bá oníbìínú ènìyàn ṣe ọ̀rẹ́; má sì ṣe bá ọkùnrin onínú-fùfù rìn.
Ṣàwárí Òwe 22:24
5
Òwe 22:9
Ẹni tí ó ní ojú àánú ni a ó bùkún fún; nítorí tí ó fi nínú oúnjẹ rẹ̀ fún olùpọ́njú.
Ṣàwárí Òwe 22:9
6
Òwe 22:3
Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ti rí ibi tẹ́lẹ̀, ó ṣé ara rẹ̀ mọ́: ṣùgbọ́n àwọn òpè tẹ̀síwájú, a sì jẹ wọ́n ní yà.
Ṣàwárí Òwe 22:3
7
Òwe 22:7
Ọlọ́rọ̀ ṣe olórí olùpọ́njú, ajigbèsè sì ṣe ìránṣẹ́ fún ẹni tí a jẹ ní gbèsè.
Ṣàwárí Òwe 22:7
8
Òwe 22:2
Ọlọ́rọ̀ àti tálákà péjọpọ̀: OLúWA ni ẹlẹ́dàá gbogbo wọn.
Ṣàwárí Òwe 22:2
9
Òwe 22:22-23
Má ṣe ja tálákà ní olè, nítorí tí ó jẹ́ tálákà: bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe ni olùpọ́njú lára ní ibodè, nítorí OLúWA yóò gbèjà wọn, yóò sì gba ọkàn àwọn tí ń gba tiwọn náà.
Ṣàwárí Òwe 22:22-23
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò