1
Ìfihàn 11:15
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Angẹli keje sì fọn ìpè; a sì gbọ́ ohùn ńlá láti ọ̀run, wí pé, “Ìjọba ayé di ti Olúwa wá, àti tí Kristi rẹ̀; òun yóò sì jẹ ọba láé àti láéláé!”
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Ìfihàn 11:15
2
Ìfihàn 11:18
Inú bí àwọn orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ̀ ti dé, àti àkókò láti dá àwọn òkú lẹ́jọ́, àti láti fi èrè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì, àti àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn tí o bẹ̀rù orúkọ rẹ̀, àti ẹni kékeré àti ẹni ńlá; àti láti run àwọn tí ń pa ayé run.”
Ṣàwárí Ìfihàn 11:18
3
Ìfihàn 11:3
Èmi ó sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹlẹ́rìí mi méjèèje, wọn ó sì sọtẹ́lẹ̀ fún ẹgbẹ̀fà ọjọ́ ó-lé-ọgọ́ta nínú aṣọ ọ̀fọ̀.”
Ṣàwárí Ìfihàn 11:3
4
Ìfihàn 11:11
Àti lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta àti ààbọ̀ náà, ẹ̀mí ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá wọ inú wọn, wọn sì dìde dúró ni ẹsẹ̀ wọn; ẹ̀rù ńlá sì ba àwọn tí o rí wọn.
Ṣàwárí Ìfihàn 11:11
5
Ìfihàn 11:6
Àwọn wọ̀nyí ni ó ni agbára láti sé ọ̀run, tí òjò kò fi lè rọ̀ ni ọjọ́ àsọtẹ́lẹ̀ wọn: Wọ́n sì ní agbára lórí omi láti sọ wọn di ẹ̀jẹ̀, àti láti fi onírúurú àjàkálẹ̀-ààrùn kọlu ayé, nígbàkúgbà tí wọ́n bá fẹ́.
Ṣàwárí Ìfihàn 11:6
6
Ìfihàn 11:4-5
Wọ̀nyí ni igi olifi méjì náà, àti ọ̀pá fìtílà méjì náà tí ń dúró níwájú Olúwa ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá sì fẹ́ pa wọn lára, iná ó ti ẹnu wọn jáde, a sì pa àwọn ọ̀tá wọn run: báyìí ni a ó sì pa ẹnikẹ́ni tí ó ba ń fẹ́ pa wọn lára run.
Ṣàwárí Ìfihàn 11:4-5
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò