A sì fi apá ìyẹ́ méjì tí idì ńlá náà fún obìnrin náà, pé kí ó fò lọ sí aginjù, sí ipò rẹ̀, níbi tí a ó gbe bọ ọ fún àkókò kan àti fún àwọn àkókò, àti fún ìdajì àkókò kúrò lọ́dọ̀ ejò náà. Ejò náà sì tu omi jáde láti ẹnu rẹ̀ wá bí odò ńlá sẹ́yìn obìnrin náà, kí ó lè fi ìṣàn omi náà gbà á lọ. Ilẹ̀ sì ran obìnrin náà lọ́wọ́, ilẹ̀ sì ya ẹnu rẹ̀, ó sì fi ìṣàn omi náà mú, tí dragoni náà tu jáde láti ẹnu rẹ̀ wá.