1
Titu 2:11-12
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní
Nítorí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tó mú ìgbàlà wà ti fi ara hàn fún gbogbo ènìyàn. Ó ń kọ́ wa láti sẹ́ àìwà-bí-Ọlọ́run àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ayé, kí a sì máa wà ní àìrékọjá, ní òdodo àti ní ìwà-bí-Ọlọ́run ní ayé ìsinsin yìí
Ṣe Àfiwé
Ṣàwárí Titu 2:11-12
2
Titu 2:13-14
bí a ti ń wọ́nà fún ìrètí tó ní bùkún, èyí ń ní ìfarahàn ògo Ọlọ́run wa tí ó tóbi àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi. Ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún wa láti rà fún ìràpadà kúrò nínú ìwà búburú gbogbo àti kí ó sì le wẹ̀ àwọn ènìyàn kan mọ́ fún ara rẹ̀ fún ìní ohun tìkára rẹ̀, àwọn tó ń ní ìtara fún iṣẹ́ rere.
Ṣàwárí Titu 2:13-14
3
Titu 2:7-8
Nínú ohun gbogbo fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí alápẹẹrẹ ohun rere. Nínú ẹ̀kọ́ rẹ fi àpẹẹrẹ ìwà pípé hàn, ẹni tó kún ojú òṣùwọ̀n ọ̀rọ̀ tí ó yè kooro, tí a kò lè dá lẹ́bi, kí ojú kí ó ti ẹni tí ó ń sòdì, ní àìní ohun búburú kan láti wí sí wa.
Ṣàwárí Titu 2:7-8
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò