KỌRINTI KINNI 12
12
Àwọn Ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́
1Ẹ̀yin ará, n kò fẹ́ kí nǹkan nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ ṣókùnkùn si yín. 2Ẹ mọ̀ pé nígbà tí ẹ jẹ́ aláìmọ Ọlọrun, ẹ̀ ń bọ oriṣa tí kò lè fọhùn. À ń tì yín síwá sẹ́yìn. 3Nítorí náà, mò ń fi ye yín pé kò sí ẹni tí ó lè máa fi agbára Ẹ̀mí Ọlọrun sọ̀rọ̀ tí ó jẹ́ fi Jesu gégùn-ún, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè wí pé, “Jesu ni Oluwa,” láìjẹ́ pé Ẹ̀mí Mímọ́ bá darí rẹ̀.
4Oríṣìíríṣìí ni ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ ṣugbọn láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà ni wọ́n ti ń wá. 5Oríṣìíríṣìí iṣẹ́ iranṣẹ ni ó wà, ṣugbọn Oluwa kan náà ni à ń sìn. 6Oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ni ó wà, ṣugbọn Ọlọrun kan náà ní ń ṣe ohun gbogbo ninu gbogbo eniyan. 7Iṣẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ń farahàn ninu olukuluku wa fún ire gbogbo wa. 8Nítorí láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ni a ti fún ẹnìkan ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n, a sì fún ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn ọ̀rọ̀ ìmọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà. 9Ẹlòmíràn ní igbagbọ, láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti ṣe ìwòsàn, láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan náà; 10ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn àtiṣe iṣẹ́ ìyanu, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn iwaasu, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn òye láti mọ ìyàtọ̀ láàrin ẹ̀mí òtítọ́ ati ẹ̀mí èké, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti fi èdè àjèjì sọ̀rọ̀, ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn láti túmọ̀ àwọn èdè àjèjì. 11Ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan ṣoṣo ni gbogbo ẹ̀bùn wọnyi ti wá; bí ó sì ti wù ú ni ó pín wọn fún ẹnìkọ̀ọ̀kan.#Rom 12:6-8
Gbogbo Ìjọ Jẹ́ Ẹ̀yà Ara Kan
12Nítorí gẹ́gẹ́ bí ara ti jẹ́ ọ̀kan, tí ó ní ọpọlọpọ ẹ̀yà, bí gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ti pọ̀ tó, sibẹ tí ara jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo, bẹ́ẹ̀ ni Kristi rí.#Rom 12:4-5 13Nítorí nípa Ẹ̀mí kan ni gbogbo wa fi ṣe ìrìbọmi tí a fi di ara kan, ìbáà ṣe pé a jẹ́ Juu tabi Giriki, à báà jẹ́ ẹrú tabi òmìnira, ninu Ẹ̀mí kan ṣoṣo ni a ti fún gbogbo wa mu.
14Nítorí kì í ṣe ẹ̀yà kan ṣoṣo ni ara ní; wọ́n pọ̀. 15Bí ẹsẹ̀ bá sọ pé, “Èmi kì í ṣe ọwọ́, nítorí náà èmi kò sí ninu ara,” èyí kò wí pé kì í tún ṣe ẹ̀yà ara mọ́. 16Bí etí bá sọ pé, “Èmi kì í ṣe ojú, nítorí náà èmi kò sí ninu ara,” kò wí pé kí ó má ṣe ẹ̀yà ara mọ́. 17Bí gbogbo ara bá jẹ́ ojú, báwo ni yóo ti ṣe gbọ́ràn? Bí gbogbo ara bá jẹ́ etí, báwo ni yóo ti ṣe gbóòórùn? 18Ṣugbọn lóòótọ́ ni, Ọlọrun fi àwọn ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan sí ipò wọn bí ó ti wù ú. 19Bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀yà kan ṣoṣo ni gbogbo ara ní, níbo ni ara ìbá wà? 20Bí ó ti wà yìí, ẹ̀yà pupọ ni ó ní, ṣugbọn ara kan ṣoṣo ni.
21Ojú kò lè wí fún ọwọ́ pé, “N kò nílò rẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni orí kò lè wí fún ẹsẹ̀ pé, “N kò nílò yín.” 22Kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn ẹ̀yà ara tí kò lágbára jẹ́ àwọn tí a kò lè ṣe aláìní. 23Àwọn ẹ̀yà mìíràn tí a rò pé wọn kò dùn ún wò ni à ń dá lọ́lá jù. Àwọn ẹ̀yà ara tí kò dùn ún wò ni à ń yẹ́ sí jùlọ. 24Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹ̀yà ara tí ó dùn ún wò kò nílò ọ̀ṣọ́ lọ títí. Ọlọrun ti ṣe ètò àwọn ẹ̀yà ara ní ọ̀nà tí ó fi fi ọlá fún àwọn ẹ̀yà tí kò dùn ún wò, 25kí ó má baà sí ìyapa ninu ara, ṣugbọn kí gbogbo àwọn ẹ̀yà ara lè máa ṣe aájò kan náà fún ara wọn. 26Bí ẹ̀yà ara kan bá ń jẹ ìrora, gbogbo àwọn ẹ̀yà yòókù níí máa bá a jẹ ìrora. Bí ara bá tu ẹ̀yà kan, gbogbo àwọn ẹ̀yà yòókù ni yóo máa bá a yọ̀.
27Ẹ̀yin ni ara Kristi, ẹ̀yà ara rẹ̀ ni ẹnìkọ̀ọ̀kan yín. 28Oríṣìíríṣìí eniyan ni Ọlọrun yàn ninu ìjọ: àwọn kinni ni àwọn aposteli, àwọn keji, àwọn wolii; àwọn kẹta, àwọn olùkọ́ni; lẹ́yìn náà, àwọn oníṣẹ́ ìyanu, kí ó tó wá kan àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn láti ṣe ìwòsàn tabi àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ẹlòmíràn, tabi àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn láti darí ètò iṣẹ́ ìjọ, ati àwọn tí wọ́n ní ẹ̀bùn láti sọ èdè àjèjì.#Efe 4:11 29Gbogbo yín ni aposteli bí? Àbí gbogbo yín ni wolii? Ṣé gbogbo yín ni olùkọ́ni? Àbí gbogbo yín ni ẹ lè ṣe iṣẹ́ ìyanu? 30Kì í ṣe gbogbo yín ni ẹ ní ẹ̀bùn kí á ṣe ìwòsàn. Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe gbogbo yín ni ẹ lè sọ èdè àjèjì. Àbí gbogbo yín ni ẹ lè túmọ̀ àwọn èdè àjèjì? 31Ẹ máa fi ìtara lépa àwọn ẹ̀bùn tí ó ga jùlọ.
Ṣugbọn n óo fi ọ̀nà kan tí ó dára jùlọ hàn yín.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
KỌRINTI KINNI 12: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010