KỌRINTI KINNI 2

2
Paulu Ń Waasu Kristi Tí Wọ́n Kàn Mọ́ Agbelebu
1Ẹ̀yin ará, nígbà tí mo dé ọ̀dọ̀ yín, n kò wá fi ọ̀rọ̀ dídùn tabi ọgbọ́n eniyan kéde àṣírí Ọlọrun fun yín. 2Nítorí mo ti pinnu pé n kò fẹ́ mọ ohunkohun láàrin yín yàtọ̀ fún Jesu Kristi: àní, ẹni tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu. 3Pẹlu àìlera ati ọpọlọpọ ìbẹ̀rù ati ìkọminú ni mo fi wá sọ́dọ̀ yín.#A. Apo 18:9 4Ọ̀rọ̀ mi ati iwaasu mi kì í ṣe láti fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí ó dùn létí yi yín lọ́kàn pada, iṣẹ́ Ẹ̀mí ati agbára Ọlọrun ni mo fẹ́ fihàn; 5kí igbagbọ yín má baà dúró lórí ọgbọ́n eniyan bíkòṣe lórí agbára Ọlọrun.
Àṣírí Tí Ẹ̀mí Ọlọrun Fihàn
6À ń sọ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n fún àwọn tí igbagbọ wọn ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, ṣugbọn kì í ṣe ọgbọ́n ti ayé yìí, kì í sìí ṣe ti àwọn aláṣẹ ayé yìí, agbára tiwọn ti fẹ́rẹ̀ pin. 7Ṣugbọn à ń sọ̀rọ̀ ọgbọ́n Ọlọrun, ohun àṣírí tí ó ti wà ní ìpamọ́, tí Ọlọrun ti ṣe ètò sílẹ̀ láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé fún ògo wa. 8Kò sí ọ̀kan ninu àwọn aláṣẹ ayé yìí tí ó mọ àṣírí yìí, nítorí tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀ ọ́n ni, wọn kì bá tí kan Oluwa tí ó lógo mọ́ agbelebu.#Bar 3:14-17 9Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé,
“Ohun tí ojú kò ì tíì rí, tí etí kò ì tíì gbọ́,
Ohun tí kò wá sí ọkàn ẹ̀dá kan rí,
ni ohun tí Ọlọrun ti pèsè sílẹ̀ fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀.”#Ais 64:4; Sir 1:9-10
10Nǹkan yìí ni Ọlọrun fi àṣírí rẹ̀ hàn wá nípa Ẹ̀mí. Ẹ̀mí ní ń wádìí ohun gbogbo títí fi kan àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọrun. 11Nítorí ẹ̀dá alààyè wo ni ó mọ ohun tí ó wà ninu eniyan kan bíkòṣe ẹ̀mí olúwarẹ̀ tí ó wà ninu rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwọn nǹkan Ọlọrun: kò sí ẹni tí ó mọ̀ wọ́n àfi Ẹ̀mí Ọlọrun. 12Ṣugbọn ní tiwa, kì í ṣe ẹ̀mí ti ayé ni a gbà. Ẹ̀mí láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni ó fi fún wa, kí á lè mọ àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọrun ti fún wa.
13Ohun tí à ń sọ kì í ṣe ohun tí eniyan fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n kọ́ wa. Ẹ̀mí ni ó kọ́ wa bí a ti ń túmọ̀ nǹkan ti ẹ̀mí, fún àwọn tí wọ́n ní Ẹ̀mí. 14Ṣugbọn eniyan ẹlẹ́ran-ara kò lè gba àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí Ọlọrun, nítorí bí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni yóo rí lójú rẹ̀. Kò tilẹ̀ lè yé e, nítorí pé ẹni tí ó bá ní Ẹ̀mí ni ó lè yé. 15Ẹni tí ó bá ní Ẹ̀mí lè wádìí ohun gbogbo, ṣugbọn eniyan kan lásán kò lè wádìí òun alára. 16Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,
“Ta ni ó mọ inú Oluwa?
Ta ni yóo kọ́ Oluwa lẹ́kọ̀ọ́?”
Ṣugbọn irú ẹ̀mí tí Kristi ní ni àwa náà ní.#Ais 40:13

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

KỌRINTI KINNI 2: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀