JOHANU KINNI 5

5
Igbagbọ ni Ìṣẹ́gun lórí Ayé
1Gbogbo ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Jesu ni Mesaya, a bí i láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ràn baba yóo fẹ́ràn Ọmọ rẹ̀. 2Ọ̀nà tí a fi lè mọ̀ pé a fẹ́ràn àwọn ọmọ Ọlọrun ni pé kí á fẹ́ràn Ọlọrun kí á sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. 3Fífẹ́ràn Ọlọrun ni pé kí á pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́: àwọn àṣẹ rẹ̀ kò sì wọni lọ́rùn,#Joh 14:15 4nítorí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọrun ti ṣẹgun ayé. Igbagbọ wa ni ìṣẹ́gun lórí ayé. 5Ta ni ó ti ṣẹgun ayé? Àfi ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu.
Ẹ̀rí nípa Ọmọ
6Òun yìí ni ó wà nípa omi ati ẹ̀jẹ̀, àní Jesu Kristi. Kì í ṣe nípa omi nìkan, ṣugbọn nípa omi ati ẹ̀jẹ̀. Ẹ̀mí ni ó ń jẹ́rìí, nítorí òtítọ́ ni Ẹ̀mí. 7Àwọn ẹlẹ́rìí mẹta ni ó wà: 8Ẹ̀mí, omi ati ẹ̀jẹ̀. Nǹkankan náà ni àwọn mẹtẹẹta ń tọ́ka sí. 9À ń gba ẹ̀rí eniyan, ṣugbọn ẹ̀rí Ọlọrun tóbi ju ti eniyan lọ; nítorí ẹ̀rí Ọlọrun ni, tí ó jẹ́ nípa Ọmọ rẹ̀. 10Ẹni tí ó bá gba Ọmọ Ọlọrun gbọ́ ní ẹ̀rí yìí ninu ara rẹ̀. Ẹni tí kò bá gba Ọlọrun gbọ́ mú Ọlọrun lékèé, nítorí kò gba ẹ̀rí tí Ọlọrun ti jẹ́ nípa Ọmọ rẹ̀ gbọ́. 11Ẹ̀rí náà ni pé Ọlọrun ti fún wa ní ìyè ainipẹkun, ìyè yìí sì wà ninu Ọmọ rẹ̀.#Joh 3:36 12Ẹni tí ó bá ní Ọmọ ní ìyè; ẹni tí kò bá ní Ọmọ Ọlọrun kò ní ìyè.
Ìyè Ainipẹkun
13Mo kọ èyí si yín, ẹ̀yin tí ẹ gba orúkọ Ọmọ Ọlọrun gbọ́, kí ẹ lè mọ̀ pé ẹ ní ìyè ainipẹkun. 14Ìgboyà tí a ní níwájú Ọlọrun nìyí, pé bí a bá bèèrè ohunkohun ní ọ̀nà tí ó fẹ́, yóo gbọ́ tiwa. 15Bí a bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ tiwa nípa ohunkohun tí a bá bèèrè, a mọ̀ pé à ń rí gbogbo ohun tí a bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ gbà.
16Bí ẹnikẹ́ni bá rí arakunrin rẹ̀ tí ó ń dẹ́ṣẹ̀ kan, tí kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ tí ó jẹ mọ́ ti ikú, kí ó gbadura fún un, Ọlọrun yóo fún un ní ìyè. Mò ń sọ nípa àwọn tí wọn ń dẹ́ṣẹ̀ tí kò jẹ mọ́ ti ikú. Ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn wà tí ó la ti ikú lọ. N kò wí pé kí eniyan gbadura fún irú rẹ̀. 17Gbogbo aiṣododo ni ẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn wà tí kò jẹ mọ́ ti ikú.
18A mọ̀ pé kò sí ọmọ Ọlọrun kan tíí máa gbé inú ẹ̀ṣẹ̀, nítorí pé Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun ń pa á mọ́, Èṣù kò sì ní fọwọ́ kàn án.
19A mọ̀ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ti wá, ati pé gbogbo ayé patapata wà lábẹ́ Èṣù.
20A tún mọ̀ pé Ọmọ Ọlọrun ti dé, ó ti fún wa ní làákàyè kí á lè mọ ẹni Òtítọ́. À ń gbé inú Ọlọrun, àní inú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Òun ni Ọlọrun tòótọ́ ati ìyè ainipẹkun.
21Ẹ̀yin ọmọde, ẹ má bá wọn bọ oriṣa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOHANU KINNI 5: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀