Bí wọ́n ti ń pada bọ̀ wálé, lẹ́yìn tí Dafidi ti pa Goliati, àwọn obinrin jáde láti gbogbo ìlú Israẹli, wọ́n lọ pàdé Saulu ọba, pẹlu orin ati ijó, wọ́n ń lu aro, wọ́n sì ń kọrin ayọ̀ pẹlu àwọn ohun èlò orin. Bí wọ́n ti ń jó, wọ́n ń kọrin báyìí pé, “Saulu pa ẹgbẹẹgbẹrun tirẹ̀, ṣugbọn Dafidi pa ẹgbẹẹgbaarun tirẹ̀.” Inú Saulu kò dùn sí orin tí wọ́n ń kọ, inú sì bí i gidigidi. Ó ní, “Wọ́n fún Dafidi ní ẹgbẹẹgbaarun ṣugbọn wọ́n fún mi ní ẹgbẹẹgbẹrun, kí ló kù tí wọn óo fún un ju ìjọba mi lọ.” Láti ọjọ́ náà ni Saulu ti ń ṣe ìlara Dafidi. Ní ọjọ́ keji, ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun bà lé Saulu, ó sì ń sọ kántankàntan láàrin ilé rẹ̀. Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí ta hapu fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ọ̀kọ̀ kan wà lọ́wọ́ Saulu. Ó ju ọ̀kọ̀ náà, ó ní kí òun fi gún Dafidi ní àgúnmọ́ ògiri. Ó ju ọ̀kọ̀ náà nígbà meji, ṣugbọn Dafidi yẹ̀ ẹ́ lẹẹmejeeji. Saulu bẹ̀rù Dafidi nítorí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀, ṣugbọn OLUWA kọ òun sílẹ̀. Saulu mú un kúrò lọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó fi ṣe olórí ẹgbẹrun ọmọ ogun, Dafidi sì ń darí àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Ó ń ṣe àṣeyọrí nítorí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀. Saulu tún bẹ̀rù Dafidi sí i nítorí àwọn àṣeyọrí rẹ̀. Ṣugbọn gbogbo àwọn ará Israẹli ati Juda ni wọ́n fẹ́ràn Dafidi, nítorí ó jẹ́ olórí tí ń ṣe àṣeyọrí.
Kà SAMUẸLI KINNI 18
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: SAMUẸLI KINNI 18:6-16
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò