SAMUẸLI KINNI 7

7
1Àwọn ará ìlú Kiriati Jearimu wá, wọ́n gbé àpótí OLUWA náà lọ sí ilé Abinadabu, tí ń gbé orí òkè kan. Wọ́n ya Eleasari, ọmọ rẹ̀ sí mímọ́, láti máa bojútó àpótí OLUWA náà.#2Sam 6:2-4; 1Kron 13:5-7
Samuẹli Ń Ṣe Àkóso Israẹli
2Láti ìgbà náà, Kiriati Jearimu ni wọ́n gbé àpótí OLUWA sí fún nǹkan bíi ogún ọdún, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì ń ké pe OLUWA fún ìrànlọ́wọ́.
3Samuẹli bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Bí ẹ bá fẹ́ pada sọ́dọ̀ OLUWA tọkàntọkàn, ẹ gbọdọ̀ kó gbogbo oriṣa ati gbogbo ère oriṣa Aṣitarotu, tí ó wà lọ́dọ̀ yín dànù; ẹ palẹ̀ ọkàn yín mọ́ fún OLUWA, kí ẹ sì máa sin òun nìkan ṣoṣo; yóo sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.” 4Àwọn ọmọ Israẹli bá kó gbogbo oriṣa Baali ati ti Aṣitarotu wọn dànù, wọ́n sì ń sin OLUWA nìkan.
5Samuẹli ní kí wọ́n kó gbogbo eniyan Israẹli jọ sí Misipa, ó ní òun óo gbadura sí OLUWA fún wọn níbẹ̀. 6Gbogbo wọn bá péjọ sí Misipa, wọ́n pọn omi, wọ́n dà á sílẹ̀, wọ́n sì ṣe ètùtù níwájú OLUWA. Wọ́n gbààwẹ̀ ṣúlẹ̀ ọjọ́ náà, wọ́n ní, “A ti ṣẹ̀ sí OLUWA.” Samuẹli sì ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan Israẹli ní Misipa.
7Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ pé àwọn ọmọ Israẹli péjọ sí Misipa, àwọn ọba Filistini kó àwọn eniyan wọn jọ láti gbógun tì wọ́n. Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́, ẹ̀rù bà wọ́n. 8Wọ́n bá wí fún Samuẹli pé, “Má dákẹ́, gbadura sí OLUWA Ọlọrun wa, kí ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Filistia.” 9Samuẹli pa ọmọ aguntan kan tí ó ṣì ń mu ọmú, ó sun ún lódidi, ó fi rúbọ sí OLUWA. Lẹ́yìn náà, ó gbadura sí OLUWA fún ìrànlọ́wọ́ Israẹli; OLUWA sì gbọ́ adura rẹ̀. 10Nígbà tí Samuẹli ń rúbọ lọ́wọ́, àwọn ará Filistia ń súnmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli, láti bá wọn jagun. Ṣugbọn OLUWA sán ààrá lù wọ́n láti ọ̀run wá. Ìdààmú bá wọn, wọ́n sì túká pẹlu ìpayà. 11Àwọn ọmọ Israẹli bá kó ogun jáde láti Misipa, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn ọmọ ogun Filistini lọ títí wọ́n fi fẹ́rẹ̀ dé ìsàlẹ̀ Betikari, wọ́n ń pa wọ́n bí wọ́n ti ń lé wọn lọ.#Sir 46:16-18.
12Samuẹli gbé òkúta kan, ó rì í mọ́lẹ̀ láàrin Misipa ati Ṣeni, #7:12 tí à ń pè ní Jeṣana ní èdè Giriki. ó sì sọ ibẹ̀ ni Ebeneseri,#7:12 tí í ṣe òkúta ìrànlọ́wọ́. ó ní, “OLUWA ràn wá lọ́wọ́ títí dé ìhín yìí.” 13Bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan Israẹli ṣe ṣẹgun àwọn ará Filistia, wọn kò sì gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli mọ́. OLUWA n ṣe àwọn ará Filistia níbi ní gbogbo ọjọ́ ayé Samuẹli. 14Gbogbo ìlú tí àwọn Filistini ti gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Israẹli, láti Ekironi títí dé Gati, ni wọ́n dá pada fún wọn. Àwọn ọmọ Israẹli gba gbogbo ilẹ̀ wọn pada lọ́wọ́ àwọn ará Filistia. Alaafia wà láàrin àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ará Amori.
15Samuẹli jẹ́ adájọ́ ní ilẹ̀ Israẹli títí tí ó fi kú. 16Lọdọọdun níí máa ń lọ yípo Bẹtẹli, Giligali, ati Misipa, láti ṣe ìdájọ́. 17Lẹ́yìn náà, yóo pada lọ sí ilé rẹ̀, ní Rama, nítorí pé a máa dájọ́ fún àwọn eniyan níbẹ̀ pẹlu. Ó sì tẹ́ pẹpẹ kan sibẹ fún OLUWA.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

SAMUẸLI KINNI 7: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀