KRONIKA KEJI 10
10
Àwọn Ẹ̀yà Ìhà Àríwá Dìtẹ̀
(1A. Ọba 12:1-20)
1Rehoboamu lọ sí Ṣekemu, nítorí pé gbogbo Israẹli ti péjọ sibẹ láti fi jọba. 2Nígbà tí Jeroboamu, ọmọ Nebati, gbọ́, ó pada wá láti Ijipti, níbi tí ó ti sá lọ fún Solomoni. 3Àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n ranṣẹ sí i, òun ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọ sọ́dọ̀ Rehoboamu, wọ́n wí fún un pé, 4“Àjàgà tí baba rẹ gbé bọ̀ wá lọ́rùn wúwo, ṣugbọn nisinsinyii, dín wahala tí baba rẹ fi wá ṣe kù, kí o sì sọ àjàgà wa di fúfúyẹ́, a óo sì máa sìn ọ́.”
5Rehoboamu bá dáhùn pé, “Ẹ pada wá gbọ́ èsì lẹ́yìn ọjọ́ mẹta.” Àwọn eniyan náà bá lọ.
6Rehoboamu bá lọ jíròrò pẹlu àwọn àgbààgbà Israẹli tí wọ́n bá baba rẹ̀ ṣiṣẹ́ nígbà ayé rẹ̀, ó ní, “Ẹ fún mi ní ìmọ̀ràn, irú èsì wo ni ó yẹ kí n fún àwọn eniyan wọnyi?”
7Wọ́n gbà á ní ìmọ̀ràn pé, “Bí o bá ṣe dáradára sí àwọn eniyan wọnyi, tí o bá ṣe ohun tí ó tẹ́ wọn lọ́rùn, tí o sì sọ̀rọ̀ dáradára fún wọn, wọn yóo máa sìn ọ́ títí lae.”
8Ṣugbọn Rehoboamu kọ ìmọ̀ràn àwọn àgbà. Ó lọ jíròrò pẹlu àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ dàgbà pọ̀, tí wọn ń bá a ṣiṣẹ́, ó bi wọ́n pé, 9“Kí ni èsì tí ó yẹ kí n fún àwọn tí wọ́n sọ fún mi pé kí n sọ àjàgà tí baba mi gbé bọ àwọn lọ́rùn di fúfúyẹ́?”
10Àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé, “Lọ sọ fún wọn pé, ‘Ìka ọwọ́ mi tí ó kéré jù yóo tóbi ju ẹ̀gbẹ́ baba mi lọ. 11Àjàgà wúwo ni baba mi gbé bọ̀ yín lọ́rùn, ṣugbọn tèmi yóo tún wúwo ju ti baba mi lọ. Pàṣán ni baba mi fi nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni èmi óo fi ta yín.’ ”
12Ní ọjọ́ kẹta, Jeroboamu pẹlu àwọn ọmọ Israẹli bá pada wá sọ́dọ̀ Rehoboamu, gẹ́gẹ́ bí àdéhùn wọn. 13Ọba kọ ìmọ̀ràn àwọn àgbà, ó gbójú mọ́ wọn, 14ó sọ̀rọ̀ sí wọn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn tí àwọn ọ̀dọ́ fún un, ó ní, “Àjàgà wúwo ni baba mi gbé bọ̀ yín lọ́rùn, ṣugbọn èmi óo tún fi kún àjàgà náà. Pàṣán ni baba mi fi nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni èmi óo fi máa ta yín.” 15Ọba kò gbọ́ ti àwọn eniyan náà, nítorí pé ọwọ́ Ọlọrun ni àyípadà yìí ti wá, kí ó lè mú ohun tí ó ní kí wolii Ahija, ará Ṣilo, sọ fún Jeroboamu, ọmọ Nebati, ṣẹ.
16Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i pé Rehoboamu kò gbọ́ tiwọn, wọ́n dáhùn pé,
“Kí ló kàn wá pẹlu ilé Dafidi?
Kí ló pa wá pọ̀ pẹlu ọmọ Jese?
Ẹ pada sinu àgọ́ yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli
Dafidi, fọwọ́ mú ilé rẹ.”
Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá pada lọ sí ilé wọn, 17ṣugbọn Rehoboamu jọba lórí àwọn ọmọ Israẹli tí wọn ń gbé Juda.#2Sam 20:1
18Ọba rán Hadoramu tí ó jẹ́ olórí àwọn akóniṣiṣẹ́ sí àwọn ọmọ Israẹli, ṣugbọn wọ́n sọ ọ́ lókùúta pa. Rehoboamu ọba bá yára bọ́ sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sá àsálà lọ sí Jerusalẹmu. 19Láti ìgbà náà lọ ni àwọn ọmọ Israẹli ti ń bá ilé Dafidi ṣọ̀tẹ̀ títí di òní olónìí.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
KRONIKA KEJI 10: YCE
Ìsàmì-sí
Daako
Ṣe Àfiwé
Pín
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010