KRONIKA KEJI 23
23
Wọ́n Dìtẹ̀ Mọ́ Atalaya
(2A. Ọba 11:4-16)
1Ní ọdún keje Jehoiada alufaa mọ́kàn gírí, ó lọ bá àwọn marun-un ninu àwọn balogun dá majẹmu. Àwọn ni: Asaraya, ọmọ Jerohamu, Iṣimaeli ọmọ Jehohanani, Asaraya ọmọ Obedi, Maaseaya ọmọ Adaya ati Eliṣafati ọmọ Sikiri. 2Wọ́n lọ káàkiri gbogbo ilẹ̀ Juda, wọ́n lọ kó àwọn Lefi ati àwọn baálé baálé gbogbo ní Israẹli wá sí Jerusalẹmu.
3Gbogbo wọn pàdé ninu ilé Ọlọrun, wọ́n sì bá ọba dá majẹmu níbẹ̀. Jehoiada wí fún wọn pé, “Ẹ wò ó! Ọmọ ọba nìyí, ó tó àkókò láti fi jọba nisinsinyii, gẹ́gẹ́ bí ìlérí tí OLUWA ṣe pé ìran Dafidi ni yóo máa jọba. 4Ohun tí ẹ óo ṣe nìyí: nígbà tí àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi bá kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi, ìdámẹ́ta ninu wọn yóo máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, 5ìdámẹ́ta yóo wà ní ààfin ọba, ìdámẹ́ta tó kù yóo máa ṣọ́ Ẹnubodè Ìpìlẹ̀; gbogbo àwọn eniyan yóo sì péjọ sí gbọ̀ngàn ilé OLUWA. 6Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọnú ilé OLUWA, àfi àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́. Àwọn lè wọlé nítorí pé wọ́n mọ́. Ṣugbọn àwọn eniyan tí ó kù gbọdọ̀ pa àṣẹ OLUWA mọ́. 7Àwọn ọmọ Lefi yóo yí ọba ká láti ṣọ́ ọ, olukuluku yóo mú ohun ìjà rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n gbọdọ̀ wà pẹlu ọba níbikíbi tí ó bá ń lọ. Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ wọnú ilé Ọlọrun, pípa ni kí ẹ pa á.”#2Sam 7:12
8Àwọn ọmọ Lefi ati gbogbo ọmọ Juda ṣe gẹ́gẹ́ bí Jehoiada alufaa ti pàṣẹ fún wọn. Olukuluku kó àwọn eniyan rẹ̀ tí wọ́n ṣíwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi wá, wọ́n dúró pẹlu àwọn tí wọ́n fẹ́ gba ipò wọn, nítorí Jehoiada alufaa kò jẹ́ kí wọ́n túká. 9Jehoiada fún àwọn ọ̀gágun ní ọ̀kọ̀ ati apata Dafidi tí wọ́n ti kó pamọ́ sinu ilé Ọlọrun. 10Ó ní kí àwọn eniyan náà dúró, kí wọn máa ṣọ́ ọba, olukuluku pẹlu ohun ìjà lọ́wọ́. Wọ́n tò láti ìhà gúsù ilé náà títí dé ìhà àríwá, ati ní àyíká pẹpẹ ati ti ilé náà. 11Jehoiada bá mú Joaṣi jáde, ó gbé adé lé e lórí, ó fún un ní ìwé òfin. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe fi Joaṣi jọba, Jehoiada alufaa ati àwọn ọmọ rẹ̀ sì fi àmì òróró yàn án lọ́ba. Gbogbo eniyan hó pé, “Kí ọba pẹ́.”
12Nígbà tí Atalaya gbọ́ híhó àwọn eniyan, ati bí wọ́n ti ń sá kiri tí wọ́n sì ń yin ọba, ó lọ sí ilé OLUWA níbi tí àwọn eniyan péjọ sí, 13ó rí i tí ọba náà dúró lẹ́bàá òpó lẹ́nu ọ̀nà, àwọn ọ̀gágun ati àwọn tí wọn ń fọn fèrè dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Gbogbo eniyan ń hó ìhó ayọ̀, wọ́n ń fọn fèrè, àwọn tí ń lo ohun èlò orin ń fi wọ́n kọrin, àwọn eniyan sì ń gberin. Nígbà tí Atalaya rí nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ẹ̀rù bà á, ó sì kígbe lóhùn rara pé, “Ọ̀tẹ̀ nìyí! Ọ̀tẹ̀ nìyí!”
14Jehoiada bá rán àwọn ọ̀gágun ọmọ ogun ọgọrun-un pé, “Ẹ fà á síta láàrin àwọn ọmọ ogun, ẹni tí ó bá tẹ̀lé e, ẹ pa á.” Nítorí àwọn alufaa ní kí wọ́n má pa á ninu tẹmpili OLUWA.
15Wọ́n bá mú un lọ sí ẹnu ọ̀nà Ẹṣin, ní ààfin, wọ́n sì pa á sibẹ.
Jehoiada Ṣe Àtúnṣe
(2A. Ọba 11:17-20)
16Jehoiada bá àwọn eniyan náà dá majẹmu pẹlu ọba, pé ti OLUWA ni àwọn yóo máa ṣe. 17Lẹ́yìn náà, gbogbo wọn lọ sí ilé oriṣa Baali, wọ́n wó o palẹ̀, wọ́n wó pẹpẹ ati àwọn ère túútúú, wọ́n sì pa Matani, tí ó jẹ́ alufaa Baali, níwájú pẹpẹ. 18Jehoiada yan àwọn aṣọ́nà fún ilé OLUWA, lábẹ́ àkóso àwọn alufaa, ọmọ Lefi, ati àwọn ọmọ Lefi tí Dafidi ti ṣètò láti máa rú ẹbọ sísun sí OLUWA bí a ti kọ ọ́ sinu ìwé òfin Mose, pẹlu àjọyọ̀ ati orin, gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti ṣètò. 19Ó fi àwọn aṣọ́nà sí ẹnu àwọn ọ̀nà ilé OLUWA kí ẹnikẹ́ni tí kò bá mọ́ má baà wọlé.
20Òun pẹlu àwọn balogun, àwọn eniyan jàǹkànjàǹkàn, àwọn gomina, ati gbogbo eniyan ilẹ̀ náà mú ọba láti ilé OLUWA, wọ́n gba ẹnu ọ̀nà òkè wá sí ààfin, wọ́n sì fi í jókòó lórí ìtẹ́. 21Inú gbogbo àwọn eniyan dùn, ìlú sì rọ̀ wọ̀ọ̀, nítorí pé wọ́n ti pa Atalaya.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
KRONIKA KEJI 23: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
![None](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapistaging.com%2F58%2Fhttps%3A%2F%2Fweb-assets.youversion.com%2Fapp-icons%2Fyo.png&w=128&q=75)
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010