KỌRINTI KEJI 9:10-11

KỌRINTI KEJI 9:10-11 YCE

Ṣugbọn ẹni tí ó ń pèsè irúgbìn fún afunrugbin, tí ó tún ń pèsè oúnjẹ fún jíjẹ, yóo pèsè èso lọpọlọpọ fun yín, yóo sì mú kí àwọn èso iṣẹ́ àánú yín pọ̀ sí i. Ẹ óo jẹ́ ọlọ́rọ̀ ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ óo fi lè máa lawọ́ nígbà gbogbo. Ọpọlọpọ eniyan yóo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà tí a bá fún wọn ní ẹ̀bùn tí ẹ gbé kalẹ̀ nítorí ìlawọ́ yín.