KỌRINTI KEJI 9
9
Ọrẹ fún Àwọn Onigbagbọ
1Nípa ti ìrànlọ́wọ́ fún àwọn onigbagbọ, kò nílò pé kí n tún kọ ìwé si yín mọ́. 2Nítorí mo mọ àníyàn yín, mo sì ti ń fi ọwọ́ sọ̀yà nípa yín fún àwọn ará Masedonia, pé Akaya ti parí ètò tiwọn láti ọdún tí ó kọjá. Ìtara yín sì ti mú kí ọpọlọpọ túbọ̀ múra sí i. 3Mo rán àwọn arakunrin sí yín, kí ọwọ́ tí a fi ń sọ̀yà nípa yín lórí ọ̀rọ̀ yìí má baà jẹ́ lásán. Gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ, kí ẹ ti múra sílẹ̀. 4Nítorí bí àwọn ará Masedonia bá bá mi wá sọ́dọ̀ yín, tí wọ́n wá rí i pé ẹ kò tíì múra sílẹ̀, ìtìjú ni yóo jẹ́ fún wa, kí á má wá sọ tiyín, nígbà tí a ti fi ọkàn tan yín lórí ọ̀rọ̀ yìí. 5Nítorí náà, mo rí i pé ó di dandan pé kí n bẹ àwọn arakunrin láti ṣiwaju mi wá sọ́dọ̀ yín, kí wọ́n ṣe ètò sílẹ̀ nípa ẹ̀bùn tí ẹ ti ṣe ìlérí, kí ó jẹ́ pé yóo ti wà nílẹ̀ kí n tó dé. Èyí yóo mú kí ó jẹ́ ọrẹ àtinúwá, kò ní jẹ́ ti ìlọ́ni-lọ́wọ́-gbà.
6Ẹ ranti pé ẹni tí ó bá fúnrúgbìn díẹ̀, díẹ̀ ni yóo kórè. Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn pupọ, pupọ ni yóo kórè. 7Kí olukuluku ṣe bí ó bá ti pinnu ninu ọkàn rẹ̀, kì í ṣe pẹlu ìkanra, tabi àfipáṣe, nítorí onínúdídùn ọlọ́rẹ ni Ọlọrun fẹ́.#Sir 20:10-15 8Ọlọrun lè fun yín ní oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn, tí ẹ óo fi ní ànító ninu ohun gbogbo nígbà gbogbo. Ẹ óo sì tún ní tí yóo ṣẹ́kù fún ohun rere gbogbo. 9Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ẹnìkan lawọ́, ó ń ta àwọn talaka lọ́rẹ, iṣẹ́ àánú rẹ̀ wà títí.”#O. Daf 112:9 10Ṣugbọn ẹni tí ó ń pèsè irúgbìn fún afunrugbin, tí ó tún ń pèsè oúnjẹ fún jíjẹ, yóo pèsè èso lọpọlọpọ fun yín, yóo sì mú kí àwọn èso iṣẹ́ àánú yín pọ̀ sí i.#Ais 55:10 11Ẹ óo jẹ́ ọlọ́rọ̀ ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ óo fi lè máa lawọ́ nígbà gbogbo. Ọpọlọpọ eniyan yóo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà tí a bá fún wọn ní ẹ̀bùn tí ẹ gbé kalẹ̀ nítorí ìlawọ́ yín. 12Nítorí kì í ṣe àìní àwọn onigbagbọ nìkan ni iṣẹ́ ìsìn yìí yóo pèsè fún, ṣugbọn yóo mú kí ọpọlọpọ eniyan máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun. 13Nítorí iṣẹ́ yìí jẹ́ ẹ̀rí tí àwọn eniyan yóo fi máa yin Ọlọrun fún rírẹ̀ tí ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ ní ìgbọràn gẹ́gẹ́ bí ìjẹ́wọ́ igbagbọ yín ninu ìyìn rere ti Kristi, ati nítorí ìlawọ́ yín ninu iṣẹ́ yìí fún wọn ati fún gbogbo onigbagbọ. 14Wọn yóo wá máa gbadura fun yín, ọkàn wọn yóo fà sọ́dọ̀ yín nítorí ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun lórí yín. 15Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun nítorí ẹ̀bùn rẹ̀ tí kò ní òǹkà.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
KỌRINTI KEJI 9: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010