KỌRINTI KEJI 10

10
Paulu Gbèjà Ara Rẹ̀
1Èmi Paulu fi ìrẹ̀lẹ̀ Kristi ati àánú rẹ̀ bẹ̀ yín, èmi tí ẹ̀ ń sọ pé nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín mo jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ṣugbọn nígbà tí mo bá kúrò lọ́dọ̀ yín mo di ògbójú si yín. 2Mo bẹ̀ yín, ẹ má ṣe jẹ́ kí n wá sọ́dọ̀ yín pẹlu ìgbójú, nítorí ó dá mi lójú pé mo lè ko àwọn kan, tí wọ́n sọ pé à ń hùwà bí ẹni tí ó ń wá ire ara wa lójú. 3Nítorí à ń gbé ìgbé-ayé wa ninu àìlera ti ara, ṣugbọn a kò jagun gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ń wá ire ara wa, 4nítorí àwọn ohun-ìjà wa kì í ṣe ti ayé, agbára Ọlọrun ni, tí a lè fi wó ìlú olódi. À ń bi gbogbo iyàn jíjà lórí èké ṣubú, 5ati gbogbo ìdínà tí ó bá gbórí sókè tí ó lòdì sí ìmọ̀ Ọlọrun. A mú gbogbo èrò ọkàn ní ìgbèkùn kí ó lè gbọ́ràn sí Kristi lẹ́nu. 6A sì ti múra tán láti jẹ gbogbo aláìgbọràn níyà, nígbà tí ẹ bá ti fi ara yín sábẹ́ wa.
7Nǹkan ti òde ara nìkan ni ẹ̀ ń wò! Bí ẹnikẹ́ni bá dá ara rẹ̀ lójú pé òun jẹ́ ti Kristi, kí ó tún inú ara rẹ̀ rò wò, nítorí bí ó ti jẹ́ ti Kristi, bẹ́ẹ̀ gan-an ni àwa náà jẹ́. 8Nítorí ojú kò tì mí bí mo bá ń ṣe ìgbéraga ní àṣejù nípa àṣẹ tí a ní, tí Oluwa fi fún mi, láti lè mu yín dàgbà ni, kì í ṣe láti fi bì yín ṣubú. 9N kò fẹ́ kí ẹ rò pé mò ń fi àwọn ìwé tí mò ń kọ dẹ́rù bà yín. 10Nítorí àwọn kan ń sọ pé, “Àwọn ìwé tí Paulu kọ jinlẹ̀, wọ́n sì le, ṣugbọn bí ẹ bá rí òun alára, bí ọlọ́kùnrùn ni ó rí, ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò sì ta eniyan lára.” 11Kí ẹni tí ó bá ń rò báyìí mọ̀ pé bí a ti jẹ́ ninu ọ̀rọ̀ tí a kọ sinu ìwé nígbà tí a kò sí lọ́dọ̀ yín, bẹ́ẹ̀ náà ni a jẹ́ ninu iṣẹ́ wa nígbà tí a bá wà lọ́dọ̀ yín.
12Nítorí a kò gbọdọ̀ da ara wa mọ́ àwọn kan tí wọn ń yin ara wọn, tabi kí á fara wé wọn. Fúnra wọn ni wọ́n ṣe òṣùnwọ̀n tí wọ́n fi ń wọn ara wọn, àwọn tìkalára wọn náà ni wọ́n sì ń fi ara wọn wé. Wọn kò lóye. 13Ṣugbọn ní tiwa, a kò ní lérí ju bí ó ti yẹ lọ. Òṣùnwọ̀n wa kò tayọ ààlà tí Ọlọrun ti pa sílẹ̀ fún wa, tí a fi mú ìyìn rere dé ọ̀dọ̀ yín. 14Nítorí kì í ṣe pé a kọjá àyè wa nígbà tí a dé ọ̀dọ̀ yín, àwa ni a sì kọ́kọ́ mú ìyìn rere Kristi dé ọ̀dọ̀ yín. 15A kò gbọdọ̀ ṣe ìgbéraga pupọ ju bí ó ti yẹ lọ lórí iṣẹ́ àwọn ẹlòmíràn. A ní ìrètí pé bí igbagbọ yín ti ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ ni ipò wa pẹlu yín yóo máa ga sí i, gẹ́gẹ́ bí ààyè wa. 16A óo wá mú ọ̀rọ̀ ìyìn rere kọjá ọ̀dọ̀ yín, láì ṣe ìgbéraga nípa iṣẹ́ tí ẹlòmíràn ti ṣe ní ààyè tirẹ̀.
17Ṣugbọn ẹni tí yóo bá ṣe ìgbéraga, Oluwa ni kí ó fi ṣe ìgbéraga.#Jer 9:24 18Kì í ṣe ẹni tí ó yin ara rẹ̀ ni ó yege, bíkòṣe ẹni tí Oluwa bá yìn.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

KỌRINTI KEJI 10: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀