PETERU KEJI 1
1
Ìkíni
1Èmi, Simoni Peteru iranṣẹ ati aposteli Jesu Kristi, ni mò ń kọ ìwé yìí sí àwọn tí wọn ní irú anfaani tí a níláti gbàgbọ́ bíi tiwa, nípa òdodo Ọlọrun wa ati ti Olùgbàlà wa Jesu Kristi.
2Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia pọ̀ sí i fun yín nípa mímọ Ọlọrun ati Jesu Oluwa wa.
Ìpè ati Yíyàn Onigbagbọ
3Nípa agbára Ọlọrun tí kì í ṣe ti eniyan, ó ti fún wa ní ohun gbogbo tí yóo jẹ́ kí á gbé irú ìgbé-ayé tí ó dára ati ti ìwà-bí-Ọlọrun, nípa mímọ ẹni tí ó fi ògo ati ọlá rẹ̀ pè wá. 4Nípasẹ̀ èyí ni a ti gba àwọn ìlérí iyebíye tí ó tóbi jùlọ, tí ó fi jẹ́ pé ẹ ti di alábàápín ninu ìwà Ọlọrun, ẹ sì ti sá fún ìbàjẹ́ tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti mú wọ inú ayé. 5Nítorí èyí, kí ẹ ní ìtara láti fi ìwà ọmọlúwàbí kún igbagbọ yín, kí ẹ sì fi ìmọ̀ kún ìwà ọmọlúwàbí. 6Ẹ fi ìkóra-ẹni-níjàánu kún ìmọ̀, kí ẹ fi ìgboyà kún ìkóra-ẹni-níjàánu, kí ẹ sì fi ìfọkànsìn kún ìgboyà. 7Ẹ fi ìṣoore fún àwọn onigbagbọ kún ìfọkànsìn, kí ẹ sì fi ìfẹ́ kún ìṣoore fún àwọn onigbagbọ. 8Nítorí tí ẹ bá ní àwọn nǹkan wọnyi; tí wọn ń dàgbà ninu yín, ìgbé-ayé yín kò ní jẹ́ lásán tabi kí ó jẹ́ aláìléso ninu mímọ Jesu Kristi. 9Afọ́jú ni ẹni tí kò bá ní àwọn nǹkan wọnyi, olúwarẹ̀ kò ríran jìnnà, kò sì lè ronú ẹ̀yìn-ọ̀la. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti gbàgbé ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́.
10Ẹ̀yin ará, ìdí rẹ̀ nìyí tí ẹ fi gbọdọ̀ túbọ̀ ní ìtara láti fi pípè tí a pè yín ati yíyàn tí a yàn yín hàn. Tí ẹ bá ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi, ẹ kò ní kùnà. 11Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ti ṣe ní ẹ̀tọ́ láti rìn gaara wọ ìjọba ayérayé ti Oluwa wa, ati Olùgbàlà Jesu Kristi.
12Nítorí náà ni mo ṣe pinnu pé n óo máa ran yín létí gbogbo nǹkan wọnyi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti mọ̀ wọ́n, ẹ sì ti fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu òtítọ́ tí ẹ ti mọ̀. 13Nítorí mo kà á sí ẹ̀tọ́ mi, níwọ̀n ìgbà tí mo wà ninu àgọ́ ara yìí, láti ji yín ninu oorun nípa rírán yín létí. 14Nítorí mo mọ̀ pé láìpẹ́ n óo bọ́ àgọ́ ara mi sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Oluwa wa Jesu Kristi ti fihàn mí. 15Ṣugbọn mò ń làkàkà pé nígbà tí mo bá lọ tán, kí ẹ ní ohun tí ẹ óo fi máa ṣe ìrántí nǹkan wọnyi nígbà gbogbo.
Ògo Kristi ati Ọ̀rọ̀ Àsọtẹ́lẹ̀
16Kì í ṣe ìtàn àròsọ ni a gbójú lé nígbà tí a sọ fun yín nípa agbára ati wíwá Oluwa wa Jesu Kristi, ṣugbọn ẹlẹ́rìí ọlá ńlá rẹ̀ ni a jẹ́. 17Nítorí a rí i nígbà tí ó gba ọlá ati ògo lọ́dọ̀ Ọlọrun Baba, nígbà tí ó gbọ́ ohùn láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ọlá ati ògo yẹ fún, tí ó wí pé,
“Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi,
inú mi dùn sí ọ.”
18Àwa fúnra wa gbọ́ ohùn yìí nígbà tí ó wá láti ọ̀run nítorí a wà pẹlu rẹ̀ lórí òkè mímọ́ nígbà náà.#Mat 17:1-5; Mak 9:2-7; Luk 9:28-35
19A tún rí ẹ̀rí tí ó dájú ninu àsọtẹ́lẹ̀ àwọn wolii, pé, kí ẹ ṣe akiyesi ọ̀rọ̀ yìí, nítorí ó dàbí fìtílà tí ń tàn ninu òkùnkùn, títí ilẹ̀ yóo fi mọ̀, títí ìràwọ̀ òwúrọ̀ yóo fi tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sinu ọkàn yín. 20Ṣugbọn kí ẹ kọ́kọ́ mọ èyí pé, kò sí àsọtẹ́lẹ̀ kan ninu Ìwé Mímọ́ tí ẹnìkan lè dá túmọ̀. 21Nítorí kì í ṣe nípasẹ̀ ìfẹ́ ẹnikẹ́ni ni àsọtẹ́lẹ̀ kan fi wá, nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ni àwọn eniyan fi ń sọ ọ̀rọ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Oluwa wá.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
PETERU KEJI 1: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010