PETERU KEJI 3:8-9

PETERU KEJI 3:8-9 YCE

Ẹ̀yin ará, ẹ má fi ojú fo èyí dá, pé níwájú Oluwa ọjọ́ kan dàbí ẹgbẹrun ọdún, ẹgbẹrun ọdún sì dàbí ọjọ́ kan. Oluwa kò jáfara nípa ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ti rò, ṣugbọn ó ń mú sùúrù fun yín ni. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé ṣugbọn ó fi ààyè sílẹ̀ kí gbogbo eniyan lè ronupiwada.