SAMUẸLI KEJI 16

16
Dafidi ati Siba
1Ní gẹ́rẹ́ tí Dafidi kọjá góńgó orí òkè náà, Siba, iranṣẹ Mẹfiboṣẹti pàdé rẹ̀, ó ń da àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bíi mélòó kan bọ̀ tí ó di igba (200) burẹdi rù, pẹlu ọgọrun-un ṣiiri èso resini, ati ọgọrun-un ṣiiri èso tútù mìíràn ati àpò aláwọ kan tí ó kún fún ọtí waini. 2Dafidi ọba bi í pé, “Kí ni o fẹ́ fi gbogbo nǹkan wọnyi ṣe?”#2Sam 9:9-10
Siba dá a lóhùn pé, “Mo mú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọnyi wá kí àwọn ìdílé Kabiyesi lè rí nǹkan gùn, mo mú burẹdi, ati èso wọnyi wá kí àwọn ọdọmọkunrin tí wọ́n wà pẹlu rẹ lè rí nǹkan jẹ; ati ọtí waini, kí àwọn tí àárẹ̀ bá mú ninu aṣálẹ̀ lè rí nǹkan mu.”
3Ọba tún bi í pé, “Níbo ni Mẹfiboṣẹti, ọmọ ọmọ Saulu, ọ̀gá rẹ wà?”
Siba dá a lóhùn pé, “Mẹfiboṣẹti dúró sí Jerusalẹmu; nítorí ó dá a lójú pé, nisinsinyii ni àwọn ọmọ Israẹli yóo dá ìjọba Saulu baba-baba rẹ̀ pada fún un.”#2Sam 19:25-27
4Ọba bá sọ fún Siba pé, “Gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti Mẹfiboṣẹti di tìrẹ láti ìsinsìnyìí lọ.”
Siba sọ fún ọba pé, “Kabiyesi, mo júbà, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n máa bá ojurere rẹ pàdé nígbà gbogbo.”
Dafidi ati Ṣimei
5Nígbà tí Dafidi ọba dé Bahurimu, ọkunrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣimei, ọmọ Gera, láti inú ìdílé Saulu, jáde sí i, bí ó sì ti ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ṣépè lemọ́lemọ́. 6Ó ń sọ òkúta lu Dafidi ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn eniyan ńláńlá ati ọpọlọpọ eniyan mìíràn wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji Dafidi ọba. 7Ṣimei ń wí fún Dafidi bí ó ti ń ṣépè pé, “Kúrò lọ́dọ̀ mi! Kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìwọ apànìyàn ati eniyan lásán! 8Ìwọ tí o gba ìjọba mọ́ Saulu lọ́wọ́, OLUWA ń jẹ ọ́ níyà nisinsinyii, fún ọpọlọpọ eniyan tí o pa ninu ìdílé Saulu. OLUWA sì ti fi ìjọba rẹ fún Absalomu, ọmọ rẹ, ìparun ti dé bá ọ, nítorí pé apànìyàn ni ọ́.”
9Abiṣai, ọmọ Seruaya wí fún ọba pé, “Kí ló dé tí òkú ajá lásánlàsàn yìí fi ń ṣépè lé ọba, oluwa mi? Jẹ́ kí n lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, kí n sì sọ orí rẹ̀ kalẹ̀ kúrò ní ọrùn rẹ̀.”
10Ṣugbọn ọba dáhùn pé, “Kò sí ohun tí ó kan ẹ̀yin ọmọ Seruaya ninu ọ̀rọ̀ yìí. Kí ni n óo ti ṣe yín sí, ẹ̀yin ọmọ Seruaya? Bí ó bá jẹ́ pé OLUWA ni ó sọ fún un pé kí ó máa ṣépè lé mi, ta ló ní ẹ̀tọ́ láti bèèrè pé, kí ló dé tí ó fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?” 11Dafidi sọ fún Abiṣai ati àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ṣebí ọmọ tèmi gan-an ni ó ń gbìyànjú láti pa mí yìí, kí ló dé tí ọ̀rọ̀ ti ará Bẹnjamini yìí fi wá jọ yín lójú. OLUWA ni ó ní kí ó máa ṣépè, nítorí náà, ẹ fi sílẹ̀, ẹ jẹ́ kí ó máa ṣẹ́ ẹ. 12Bóyá OLUWA lè wo ìpọ́njú mi, kí ó sì fi ìre dípò èpè tí ó ń ṣẹ́ lé mi.” 13Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ bá ń bá tiwọn lọ, Ṣimei sì ń tẹ̀lé wọn lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji òkè náà, bí ó ti ń tẹ̀lé wọn, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ṣépè, ó ń sọ òkúta lù ú, ó sì ń da erùpẹ̀ sí wọn lára. 14Nígbà tí ọba ati àwọn eniyan rẹ̀ yóo fi dé ibi odò Jọdani, ó ti rẹ̀ wọ́n, nítorí náà, wọ́n sinmi níbẹ̀.
Absalomu ní Jerusalẹmu
15Absalomu ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ wọ Jerusalẹmu lọ, Ahitofeli sì wà pẹlu wọn. 16Nígbà tí Huṣai, ará Ariki, ọ̀rẹ́ Dafidi pàdé Absalomu, ó kígbe pé “Kí ọba kí ó pẹ́! Kí ọba kí ó pẹ́!”
17Absalomu bá bi í pé, “Kí ló dé, tí o kò fi ṣe olótìítọ́ sí Dafidi ọ̀rẹ́ rẹ mọ́? Kí ló dé tí o kò fi bá a lọ?”
18Huṣai dáhùn pé, “Ẹ̀yìn ẹnikẹ́ni tí OLUWA, ati àwọn eniyan wọnyi, ati gbogbo Israẹli bá yàn ni mo wà. Tirẹ̀ ni n óo jẹ́, n óo sì dúró tì í. 19Ta ni ǹ bá tilẹ̀ tún sìn, bí kò ṣe ọmọ oluwa mi. Bí mo ti sin baba rẹ, bẹ́ẹ̀ gan-an ni n óo sin ìwọ náà.”
20Absalomu kọjú sí Ahitofeli, ó sì bi í pé, “Nígbà tí a ti dé Jerusalẹmu báyìí, kí ni ìmọ̀ràn rẹ?”
21Ahitofeli dáhùn pé, “Wọlé lọ bá àwọn obinrin baba rẹ, tí ó fi sílẹ̀ láti máa tọ́jú ààfin, kí o sì bá wọn lòpọ̀. Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli yóo wá gbà pé o ti kẹ̀yìn sí baba rẹ, ọkàn gbogbo àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ yóo sì balẹ̀.” 22Wọ́n bá pàgọ́ kan fún Absalomu, lórí òrùlé ààfin, ó wọlé lọ bá àwọn obinrin baba rẹ̀ lójú gbogbo àwọn eniyan, ó sì bá wọn lòpọ̀.#2Sam 12:11-12
23Ní àkókò náà, ìmọ̀ràn tí Ahitofeli bá dá, ni àwọn eniyan máa ń gbà, bí ẹni pé Ọlọrun gan-an ni ó ń sọ̀rọ̀; Dafidi ati Absalomu pàápàá a máa tẹ̀lé ìmọ̀ràn rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

SAMUẸLI KEJI 16: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀