SAMUẸLI KEJI 19
19
Joabu Bínú sí Dafidi
1Àwọn kan lọ sọ fún Joabu pé, ọba ń sọkún, ó sì ń ṣọ̀fọ̀ Absalomu. 2Nítorí náà, ìṣẹ́gun ọjọ́ náà pada di ìbànújẹ́ fún gbogbo àwọn eniyan; nítorí wọ́n gbọ́ pé ọba ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀. 3Àwọn ọmọ ogun náà yọ́ wọ ìlú jẹ́ẹ́, bí ẹni pé wọ́n sá lójú ogun, tí ìtìjú sì mú wọn. 4Ọba dọwọ́ bojú, ó ń sọkún, ó sì ń kígbe sókè pé, “Ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi!”
5Joabu bá wọlé tọ ọba lọ, ó wí fún un pé, “O ti dójúti àwọn ọmọ ogun rẹ lónìí, àwọn tí wọ́n gba ẹ̀mí rẹ là, ati ẹ̀mí àwọn ọmọ rẹ, ati ti àwọn aya rẹ, ati àwọn obinrin rẹ; 6nítorí pé o fẹ́ràn àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ, o sì kórìíra àwọn tí wọ́n fẹ́ràn rẹ. O ti fihàn gbangba pé, àwọn ọ̀gágun ati ọmọ ogun rẹ kò jẹ́ nǹkankan lójú rẹ. Mo ti rí i gbangba lónìí pé, ìbá dùn mọ́ ọ ninu, bí gbogbo wa tilẹ̀ kú, tí Absalomu sì wà láàyè. 7Yára dìde, kí o lọ tu àwọn ọmọ ogun ninu; nítorí pé mo fi OLUWA búra pé, bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní ku ẹnìkan ninu wọn pẹlu rẹ ní òwúrọ̀ ọ̀la. Èyí yóo wá burú ju gbogbo ibi tí ó ti bá ọ láti ìgbà èwe rẹ títí di òní lọ.” 8Ọba bá dìde, ó lọ jókòó lẹ́bàá ẹnu ọ̀nà ibodè. Àwọn eniyan rẹ̀ gbọ́ pé ó wà níbẹ̀, gbogbo wọn bá wá rọ̀gbà yí i ká.
Dafidi Bẹ̀rẹ̀ Ìrìn Àjò Rẹ̀ Pada sí Jerusalẹmu
Ní àkókò yìí, gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli ti sá, olukuluku ti pada sí ilé rẹ̀. 9Ìjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli káàkiri. Wọ́n ń wí láàrin ara wọn pé, “Ọba Dafidi ni ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, òun ni ó gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Filistia, ṣugbọn nisinsinyii, ó ti sá kúrò nílùú fún Absalomu. 10A fi àmì òróró yan Absalomu ní ọba, ṣugbọn wọ́n ti pa á lójú ogun, nítorí náà, ó yẹ kí ẹnìkan gbìyànjú láti mú Dafidi ọba pada.”
11Ìròyìn ohun tí àwọn eniyan Israẹli ń wí kan Dafidi ọba lára. Dafidi ọba ranṣẹ sí àwọn alufaa mejeeji: Sadoku, ati Abiatari, láti bèèrè lọ́wọ́ àwọn àgbààgbà Juda pé, “Kí ló dé tí ẹ fi níláti gbẹ́yìn ninu ètò àtidá ọba pada sí ààfin rẹ̀? 12Ṣebí ìbátan ọba ni yín, ẹ̀jẹ̀ kan náà sì ni yín? Kí ló dé tí ẹ fi níláti gbẹ́yìn ninu ètò àtidá ọba pada sí ààfin rẹ̀.” 13Dafidi ní kí wọ́n sọ fún Amasa pé, ẹbí òun ni Amasa; ati pé, láti ìgbà náà lọ, Amasa ni òun yóo fi ṣe balogun òun, dípò Joabu. Ó búra pé kí Ọlọrun pa òun bí òun kò bá ṣe bẹ́ẹ̀. 14Ọ̀rọ̀ tí Dafidi sọ yìí, mú kí àwọn eniyan Juda fara mọ́ ọn, wọ́n sì ranṣẹ sí i pé kí ó pada pẹlu gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀.
15Nígbà tí ọba ń pada bọ̀, àwọn eniyan Juda wá sí Giligali láti pàdé rẹ̀ ati láti mú un kọjá odò Jọdani. 16Ní àkókò yìí kan náà, Ṣimei, ọmọ Gera, ará Bẹnjamini, láti ìlú Bahurimu, sáré lọ sí odò Jọdani láti pàdé Dafidi ọba pẹlu àwọn eniyan Juda. 17Ẹgbẹrun (1,000) eniyan, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini, ni ó kó lọ́wọ́. Siba, iranṣẹ ìdílé Saulu, náà wá pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀ mẹẹdogun, ati ogún iranṣẹ. Wọ́n dé sí etí odò kí ọba tó dé ibẹ̀. 18Wọ́n rékọjá odò sí òdìkejì, láti dara pọ̀ mọ́ àwọn tí wọn yóo sin ìdílé ọba kọjá odò, ati láti ṣe ohunkohun tí ọba bá fẹ́.#2Sam 16:5-13
Dafidi Ṣàánú Ṣimei
Bí ọba ti múra láti kọjá odò náà, Ṣimei wólẹ̀ níwájú rẹ̀. 19Ó ní, “Kabiyesi, jọ̀wọ́ má dá mi lẹ́bi, má sì ranti àṣìṣe tí mo ṣe ní ọjọ́ tí o kúrò ní Jerusalẹmu, jọ̀wọ́ gbàgbé rẹ̀. 20Mo mọ̀ pé mo ti ṣẹ̀; Ìdí nìyí, tí ó fi jẹ́ pé èmi ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́ wá pàdé rẹ lónìí, ninu gbogbo ìdílé Josẹfu.”
21Abiṣai ọmọ Seruaya dáhùn pé, “Pípa ni ó yẹ kí á pa Ṣimei nítorí pé ó ṣépè lé ẹni tí OLUWA fi òróró yàn ní ọba.”
22Ṣugbọn Dafidi dá Abiṣai ati Joabu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lóhùn pé, “Kí ló kàn yín ninu ọ̀rọ̀ yìí? Kí ni n óo ti ṣe yín sí, ẹ̀yin ọmọ Seruaya, tí ẹ̀ ń ṣe bí ọ̀tá sí mi? Èmi ni ọba Israẹli lónìí, ẹnìkan kò sì ní pa ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli.” 23Ó bá dá Ṣimei lóhùn, ó ní, “Mo búra fún ọ pé ẹnikẹ́ni kò ní pa ọ́.”
Dafidi Ṣàánú Mẹfiboṣẹti
24Lẹ́yìn náà, Mẹfiboṣẹti, ọmọ ọmọ Saulu, wá pàdé ọba. Láti ìgbà tí ọba ti kúrò ní Jerusalẹmu, títí tí ó fi pada dé ní alaafia, Mẹfiboṣẹti kò fọ ẹsẹ̀ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni kò gé irùngbọ̀n rẹ̀, tabi kí ó fọ aṣọ rẹ̀. 25Nígbà tí Mẹfiboṣẹti ti Jerusalẹmu dé láti pàdé ọba, ọba bi í pé, “Mẹfiboṣẹti, kí ló dé tí o kò fi bá mi lọ?”#2Sam 9:1-13; 16:1-4
26Mẹfiboṣẹti dáhùn pé, “Kabiyesi, gẹ́gẹ́ bí ìwọ náà ti mọ̀, arọ ni mí. Mo sọ fún iranṣẹ mi pé kí ó di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ mi ní gàárì, kí n lè gùn ún tẹ̀lé ọ, ṣugbọn ó hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí mi. 27Ó lọ pa irọ́ mọ́ mi lọ́dọ̀ ọba. Ṣugbọn bí angẹli Ọlọrun ni oluwa mi, ọba rí; nítorí náà, ṣe ohun tí ó bá tọ́ sí mi ní ojú rẹ. 28Gbogbo ìdílé baba mi pátá ni ó yẹ kí o pa, ṣugbọn o gbà mí láàyè; o sì fún mi ní ẹ̀tọ́ láti máa jẹun níbi tabili rẹ. Kò yẹ mí rárá, láti tún bèèrè nǹkankan mọ́ lọ́wọ́ kabiyesi.”
29Ọba dá a lóhùn pé, “Má wulẹ̀ tún sọ nǹkankan mọ́, mo ti pinnu pé ìwọ ati Siba ni yóo pín gbogbo ogun Saulu.”
30Mẹfiboṣẹti bá dáhùn pé, “Jẹ́ kí Siba máa mú gbogbo rẹ̀, kìkì pé kabiyesi pada dé ilé ní alaafia ti tó fún mi.”
Dafidi Ṣàánú Basilai
31Basilai ará Gileadi náà wá láti Rogelimu. Ó bá ọba dé odò Jọdani láti sìn ín kọjá odò náà. 32Basilai ti darúgbó gan-an, ẹni ọgọrin ọdún ni. Ó tọ́jú nǹkan jíjẹ fún ọba nígbà tí ó fi wà ní Mahanaimu, nítorí pé ọlọ́rọ̀ ni. 33Ọba wí fún un pé, “Bá mi kálọ sí Jerusalẹmu, n óo sì tọ́jú rẹ dáradára.”#2Sam 17:27-29
34Ṣugbọn Basilai dáhùn pé, “Ọjọ́ tí ó kù fún mi láyé kò pọ̀ mọ́, kí ni n óo tún máa bá kabiyesi lọ sí Jerusalẹmu fún? 35Mo ti di ẹni ọgọrin ọdún, kò sì sí ohunkohun tí ó tún wù mí mọ́. Oúnjẹ ati ohun mímu kò dùn lẹ́nu mi mọ́. Bí àwọn akọrin ń kọrin, n kò lè gbọ́ orin wọn mọ́. Wahala lásán ni n óo lọ kó bá oluwa mi, ọba. 36Irú anfaani ńlá báyìí kò tọ́ sí mi láti ọ̀dọ̀ ọba, nítorí náà, n óo bá ọba gun òkè odò Jọdani, n óo sì bá ọ lọ sí iwájú díẹ̀ ni. 37Lẹ́yìn náà, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n pada lọ sí ilé mi, kí n lè kú sí ìlú mi, nítòsí ibojì àwọn òbí mi. Kimhamu ọmọ mi nìyí, jẹ́ kí ó máa bá ọ lọ, kí o sì ṣe ohun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ fún un.”
38Ọba dáhùn pé, “N óo máa mú Kimhamu lọ, ohunkohun tí ó bá sì bèèrè, ni n óo ṣe fún un.” 39Lẹ́yìn náà ni Dafidi ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ gòkè odò Jọdani. Ó kí Basilai, ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu, ó sì súre fún un; Basilai bá pada sí ilé rẹ̀.
Juda ati Israẹli Ń Jiyàn lórí Ẹni Tí Ó Ni Ọba
40Lẹ́yìn tí àwọn ará ilẹ̀ Juda, ati ìdajì àwọn ọmọ Israẹli ti sin ọba kọjá odò, ọba lọ sí Giligali, Kimhamu sì bá a lọ. 41Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli bá wá sọ́dọ̀ ọba, wọ́n sì bi í pé, “Kabiyesi, kí ló dé tí àwọn eniyan Juda, àwọn arakunrin wa, fi lérò pé àwọn ní ẹ̀tọ́ láti mú ọ lọ, ati láti sin ìwọ ati ìdílé rẹ, ati àwọn eniyan rẹ kọjá odò Jọdani?”
42Àwọn eniyan Juda bá dáhùn pé, “Ìdí tí a fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, ọ̀kan náà ni àwa ati ọba. Kí ló dé tí èyí fi níláti bà yín ninu jẹ́? Kì í ṣá ṣe pé òun ni ó ń bọ́ wa, a kò sì gba nǹkankan lọ́wọ́ rẹ̀.”
43Àwọn ọmọ Israẹli dáhùn pé, “Ìlọ́po mẹ́wàá ẹ̀tọ́ tí ẹ ní sí ọba ni àwa ní, kì báà tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kan náà ni yín. Kí ló dé tí ẹ fi fi ojú tẹmbẹlu wa? Ẹ má gbàgbé pé àwa ni a dábàá ati mú ọba pada sílé.”
Ṣugbọn ọ̀rọ̀ àwọn ará ilẹ̀ Juda le ju ti àwọn ará ilẹ̀ Israẹli lọ.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
SAMUẸLI KEJI 19: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
![None](/_next/image?url=https%3A%2F%2Fimageproxy.youversionapistaging.com%2F58%2Fhttps%3A%2F%2Fweb-assets.youversion.com%2Fapp-icons%2Fyo.png&w=128&q=75)
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010