SAMUẸLI KEJI 8
8
Àwọn Ogun Tí Dafidi Jà ní Àjàṣẹ́gun
(1Kron 18:1-17)
1Lẹ́yìn náà, Dafidi ọba gbógun ti àwọn ará Filistia, ó ṣẹgun wọn, ó sì gba ìlú Mẹtẹgi-ama lọ́wọ́ wọn.
2Ó ṣẹgun àwọn ará Moabu bákan náà, ó sì mú kí àwọn tí ó kó lẹ́rú ninu wọn dọ̀bálẹ̀ lórí ilẹ̀ ní ìlà mẹta, ó pa gbogbo àwọn tí wọ́n wà lórí ìlà meji, ó sì dá àwọn tí wọ́n dọ̀bálẹ̀ lórí ìlà kan sí, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Moabu ṣe di ẹrú rẹ̀, tí wọ́n sì ń san owó ìṣákọ́lẹ̀ fún un.
3Dafidi sì tún ṣẹgun Hadadeseri, ọmọ Rehobu, ọba Soba, bí ó tí ń lọ láti fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ ní ilẹ̀ tí ó wà ní agbègbè odò Yufurate. 4Ẹẹdẹgbẹsan (1,700) ẹlẹ́ṣin ni Dafidi gbà lọ́wọ́ rẹ̀, ati ọ̀kẹ́ kan àwọn ọmọ ogun tí wọ́n ń fi ẹsẹ̀ rìn. Dafidi dá ẹsẹ̀ àwọn ẹṣin tí ń fa kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ṣugbọn ó dá ọgọrun-un (100) sí ninu wọn.
5Nígbà tí àwọn ará Siria dé láti Damasku tí wọ́n ran Hadadeseri, ọba Soba lọ́wọ́, Dafidi pa ẹgbaa mọkanla (22,000) ninu àwọn ọmọ ogun wọn. 6Dafidi bá kọ́ àgọ́ àwọn ọmọ ogun kan sí Aramu, ní Damasku, gbogbo àwọn ará Siria sì ń sin Dafidi, wọ́n sì ń san owó ìṣákọ́lẹ̀ fún un. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ. 7Dafidi gba àwọn apata wúrà tí àwọn ọ̀gágun Hadadeseri fi ń jagun, ó sì kó wọn wá sí Jerusalẹmu. 8Bákan náà, Dafidi ọba kó ọpọlọpọ idẹ láti Bẹta ati Berotai, ìlú meji ninu àwọn ìlú tí ó wà lábẹ́ ìjọba Hadadeseri.
9Nígbà tí Toi ọba Hamati gbọ́ pé Dafidi ti ṣẹgun gbogbo àwọn ọmọ ogun Hadadeseri, 10ó rán Joramu ọmọ rẹ̀ láti kí Dafidi ọba kú oríire, fún ìṣẹ́gun rẹ̀ lórí Hadadeseri, nítorí pé Hadadeseri ti bá Toi jagun ní ọpọlọpọ ìgbà. Joramu mú ọpọlọpọ ẹ̀bùn tí wọ́n fi wúrà ṣe, ati ti fadaka, ati ti idẹ lọ́wọ́ fún Dafidi. 11Dafidi ọba ya àwọn ẹ̀bùn náà sí mímọ́ fún ìlò ninu ilé OLUWA, pẹlu gbogbo fadaka ati wúrà tí ó rí kó láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹgun; 12àwọn bíi: àwọn ará Edomu, àwọn ará Moabu, àwọn ará Amoni, àwọn ará Filistia, ati àwọn ará Amaleki; pẹlu ìkógun Hadadeseri, ọba Soba.
13Dafidi túbọ̀ di olókìkí sí i nígbà tí ó pada dé, láti ibi tí ó ti lọ pa ẹgbaasan-an (18,000) ninu àwọn ará Edomu, ní Àfonífojì Iyọ̀. 14Ó kọ́ ibùdó àwọn ọmọ ogun káàkiri ilẹ̀ Edomu, gbogbo àwọn ará Edomu sì ń sin Dafidi. OLUWA fún Dafidi ní ìṣẹ́gun ní gbogbo ibi tí ó lọ.#O. Daf 60: Àkọlé
15Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi ṣe jọba lórí gbogbo Israẹli, ó sì ń ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo sí gbogbo eniyan, nígbà gbogbo. 16Joabu, ọmọ Seruaya ni balogun rẹ̀, Jehoṣafati, ọmọ Ahiludi ni alákòóso gbogbo àwọn ìwé àkọsílẹ̀ rẹ̀. 17Sadoku, ọmọ Ahitubu, ati Ahimeleki, ọmọ Abiatari ni alufaa, Seraaya ni akọ̀wé gbọ̀ngàn ìdájọ́ rẹ̀. 18Bẹnaya, ọmọ Jehoiada ni olórí àwọn Kereti ati àwọn Peleti (tí ń ṣọ́ ààfin), àwọn ọmọ Dafidi ọkunrin ni wọ́n sì jẹ́ alufaa.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
SAMUẸLI KEJI 8: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010