ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 13:47-49

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 13:47-49 YCE

Nítorí bẹ́ẹ̀ ni Oluwa pa láṣẹ fún wa nígbà tí ó sọ pé: ‘Mo ti fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, kí ìgbàlà mi lè dé òpin ilẹ̀ ayé.’ ” Nígbà tí àwọn tí kì í ṣe Juu gbọ́, inú wọn dùn. Wọ́n dúpẹ́ fún ọ̀rọ̀ Oluwa. Gbogbo àwọn tí a ti yàn láti ní ìyè ainipẹkun bá gbàgbọ́. Ọ̀rọ̀ Oluwa tàn ká gbogbo ilẹ̀ náà.