Iṣe Apo 13:47-49
Iṣe Apo 13:47-49 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bẹ̃li Oluwa sá ti paṣẹ fun wa pe, Mo ti gbé ọ kalẹ fun imọlẹ awọn Keferi, ki iwọ ki o le jẹ fun igbala titi de opin aiye. Nigbati awọn Keferi si gbọ́ eyi, nwọn yọ̀, nwọn si yìn ọ̀rọ Ọlọrun logo: gbogbo awọn ti a yàn si ìye ainipẹkun si gbagbọ́. A si tàn ọ̀rọ Oluwa ka gbogbo ẹkùn na.
Iṣe Apo 13:47-49 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí bẹ́ẹ̀ ni Oluwa pa láṣẹ fún wa nígbà tí ó sọ pé: ‘Mo ti fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, kí ìgbàlà mi lè dé òpin ilẹ̀ ayé.’ ” Nígbà tí àwọn tí kì í ṣe Juu gbọ́, inú wọn dùn. Wọ́n dúpẹ́ fún ọ̀rọ̀ Oluwa. Gbogbo àwọn tí a ti yàn láti ní ìyè ainipẹkun bá gbàgbọ́. Ọ̀rọ̀ Oluwa tàn ká gbogbo ilẹ̀ náà.
Iṣe Apo 13:47-49 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ṣa ti pàṣẹ fún wa pé: “ ‘Mo ti gbé ọ kalẹ̀ láti tan ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà, kí ìwọ lè mú ìgbàlà wá títí dé òpin ayé.’ ” Nígbà tí àwọn aláìkọlà sì gbọ́ èyí, wọ́n sì yín ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lógo: gbogbo àwọn tí a yàn sí ìyè àìnípẹ̀kun sì gbàgbọ́. A sí tan ọ̀rọ̀ Olúwa ká gbogbo agbègbè náà.