Ìṣe àwọn Aposteli 13:47-49

Ìṣe àwọn Aposteli 13:47-49 YCB

Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ṣa ti pàṣẹ fún wa pé: “ ‘Mo ti gbé ọ kalẹ̀ láti tan ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà, kí ìwọ lè mú ìgbàlà wá títí dé òpin ayé.’ ” Nígbà tí àwọn aláìkọlà sì gbọ́ èyí, wọ́n sì yín ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lógo: gbogbo àwọn tí a yàn sí ìyè àìnípẹ̀kun sì gbàgbọ́. A sí tan ọ̀rọ̀ Olúwa ká gbogbo agbègbè náà.