ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 20

20
Paulu lọ sí Masedonia ati Ilẹ̀ Giriki
1Nígbà tí rògbòdìyàn náà kásẹ̀, Paulu ranṣẹ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ó gbà wọ́n níyànjú, ó sì dágbére fún wọn, ó bá lọ sí Masedonia. 2Bí ó ti ń kọjá ní gbogbo agbègbè náà, bẹ́ẹ̀ ni ó ń gba àwọn eniyan níyànjú pẹlu ọ̀rọ̀ ìwúrí pupọ títí ó fi dé ilẹ̀ Giriki. 3Ó ṣe oṣù mẹta níbẹ̀. Bí ó ti fẹ́ máa lọ sí Siria, ó rí i pé àwọn Juu ń dìtẹ̀ sí òun, ó bá gba Masedonia pada. 4Sopata ọmọ Pirusi ará Beria bá a lọ. Bẹ́ẹ̀ náà ni Arisitakọsi ati Sekundu; ará Tẹsalonika ni wọ́n. Gaiyu ará Dabe ati Timoti náà bá a lọ, ati Tukikọsi ati Tirofimọsi; àwọn jẹ́ ará Esia. 5Àwọn tí a wí yìí ṣiwaju wa lọ, wọ́n lọ dúró dè wá ní Tiroasi. 6Àwa náà wá wọkọ̀ ojú omi ní Filipi lẹ́yìn Àjọ̀dún Àìwúkàrà, a bá wọn ní Tiroasi lọ́jọ́ karun-un. Ọjọ́ meje ni a lò níbẹ̀.
Paulu Bẹ Tiroasi Wò fún Ìgbà Ìkẹyìn
7Ní alẹ́ ọjọ́ Satide, a péjọ láti jẹun; Paulu wá ń bá àwọn onigbagbọ sọ̀rọ̀. Ó ti wà lọ́kàn rẹ̀ pé lọ́jọ́ keji ni òun óo tún gbéra. Nítorí náà ó sọ̀rọ̀ títí dòru. 8Àtùpà pọ̀ ninu iyàrá òkè níbi tí a péjọ sí. 9Ọdọmọkunrin kan tí ó ń jẹ́ Yutiku jókòó lórí fèrèsé. Ó ti sùn lọ níbi tí Paulu gbé ń sọ̀rọ̀ lọ títí. Nígbà tí oorun wọ̀ ọ́ lára, ó ré bọ́ sílẹ̀ láti orí pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kẹta. Nígbà tí wọn óo gbé e, ó ti kú. 10Paulu bá sọ̀kalẹ̀, ó gbá a mú, ó dùbúlẹ̀ lé e lórí. Ó ní, “Ẹ má dààmú, nítorí ẹ̀mí rẹ̀ ṣì wà ninu rẹ̀.” 11Nígbà tí ó pada sókè, ó gé burẹdi, ó jẹun. Ó wá ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́. Ó bá jáde lọ. 12Wọ́n mú ọmọ náà lọ sílé láàyè. Èyí sì tù wọ́n ninu lọpọlọpọ.
Ìrìn Àjò láti Tiroasi Dé Miletu
13A bọ́ siwaju, a wọkọ̀ ojú omi lọ sí Asọsi. Níbẹ̀ ni a lérò pé Paulu yóo ti wá bá wa tí òun náà yóo sì wọkọ̀. Òun ló ṣe ètò bẹ́ẹ̀ nítorí ó fẹ́ fẹsẹ̀ rìn dé ibẹ̀. 14Nígbà tí ó bá wa ní Asọsi, ó wọnú ọkọ̀ wa, a bá lọ sí Mitilene. 15Ní ọjọ́ keji a kúrò níbẹ̀, a dé òdìkejì erékùṣù Kiosi. Ní ọjọ́ kẹta a dé Samosi. Ní ọjọ́ kẹrin a dé Miletu. 16Nítorí Paulu ti pinnu láti wọkọ̀ kọjá Efesu, kí ó má baà pẹ́ pupọ ní Esia, nítorí ó ń dàníyàn pé bí ó bá ṣeéṣe, òun fẹ́ ṣe Àjọ̀dún Pẹntikọsti ní Jerusalẹmu.
Paulu Bá Àwọn Alàgbà Efesu Sọ̀rọ̀
17Láti Miletu, Paulu ranṣẹ sí Efesu kí wọ́n lọ pe àwọn alàgbà ìjọ wá. 18Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ mọ̀ bí mo ti lo gbogbo àkókò mi láàrin yín láti ìgbà tí mo ti kọ́kọ́ dé ilẹ̀ Esia. 19Ẹ mọ̀ bí mo ti fi ìrẹ̀lẹ̀ ati omi ojú sin Oluwa ní ọ̀nà gbogbo ninu àwọn ìṣòro tí mo fara dà nítorí ọ̀tẹ̀ tí àwọn Juu dì sí mi. 20Ẹ mọ̀ pé n kò dánu dúró láti sọ ohunkohun fun yín tí yóo ṣe yín ní anfaani; mò ń kọ yín ní gbangba ati ninu ilé yín. 21Mò ń tẹnu mọ́ ọn fún àwọn Juu ati àwọn Giriki pé kí wọn yipada sí Ọlọrun, kí wọn ní igbagbọ ninu Oluwa Jesu. 22Nisinsinyii, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí ti darí mi, mò ń lọ sí Jerusalẹmu láì mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí mi níbẹ̀, 23àfi pé láti ìlú dé ìlú ni Ẹ̀mí Mímọ́ ń fi àmì hàn mí pé ẹ̀wọ̀n ati ìyà ń dúró dè mí níbẹ̀. 24Ṣugbọn n kò ka ẹ̀mí mi sí ohunkohun tí ó ní iye lórí fún ara mi. Ohun tí mò ń lépa ni láti parí iré ìje mi ati iṣẹ́ tí mo gbà lọ́wọ́ Oluwa mi Jesu, èyí ni pé kí n tẹnu mọ́ ìyìn rere oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun.#2 Tim 4:7
25“Wàyí ò, èmi gan-an mọ̀ pé gbogbo ẹ̀yin tí mo ti ń waasu ìjọba Ọlọrun láàrin yín kò tún ní fi ojú kàn mí mọ́. 26Nítorí náà mo sọ fun yín lónìí yìí pé bí ẹnikẹ́ni bá ṣègbé ninu yín, ẹ̀bi mi kọ́. 27Nítorí n kò dánu dúró láti sọ gbogbo ohun tí Ọlọrun fẹ́ fun yín. 28Ẹ ṣọ́ra yín, ẹ sì ṣọ́ agbo tí Ẹ̀mí Mímọ́ fi yín ṣe alabojuto lórí rẹ̀, kí ẹ máa bọ́ ìjọ Ọlọrun tí ó fi ẹ̀jẹ̀ Ọmọ rẹ̀ ṣe ní tirẹ̀. 29Mo mọ̀ pé lẹ́yìn tí mo bá lọ, àwọn ẹhànnà ìkookò yóo wọ ààrin yín; wọn kò sì ní dá agbo sí. 30Mo mọ̀ pé láàrin yín àwọn ẹlòmíràn yóo dìde tí wọn yóo fi irọ́ yí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lọ́kàn pada láti tẹ̀lé wọn. 31Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́ra. Ẹ ranti pé fún ọdún mẹta, tọ̀sán-tòru ni n kò fi sinmi láti máa gba ẹnìkọ̀ọ̀kan yín níyànjú pẹlu omi lójú.
32“Nisinsinyii, mo fi yín lé Ọlọrun lọ́wọ́ ati ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ tí ó lè mu yín dàgbà, tí ó sì lè fun yín ní ogún pẹlu gbogbo àwọn tí a ti sọ di mímọ́. 33N kò ṣe ojúkòkòrò owó tabi aṣọ tabi góòlù ẹnikẹ́ni. 34Ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé ọwọ́ ara mi yìí ni mo fi ṣiṣẹ́ tí mo fi ń gbọ́ bùkátà mi ati ti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi. 35Mo ti fihàn yín pé bẹ́ẹ̀ ni a níláti ṣiṣẹ́ láti ran àwọn aláìlera lọ́wọ́. Kí á máa ranti àwọn ọ̀rọ̀ Oluwa Jesu, nítorí òun fúnra rẹ̀ sọ pé, ‘Ayọ̀ pọ̀ ninu kí a máa fúnni ní nǹkan ju kí á máa gbà lọ.’ ”
36Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó kúnlẹ̀ pẹlu gbogbo wọn, ó sì gbadura. 37Gbogbo wọn bá ń sunkún. Wọ́n ń dì mọ́ ọn, wọ́n ń fi ẹnu kò ó lẹ́nu. 38Èyí tí ó dùn wọ́n jù ni ọ̀rọ̀ tí ó sọ, pé wọn kò tún ní rí ojú òun mọ́. Wọ́n bá sìn ín lọ sí ìdíkọ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 20: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀