ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 25

25
Paulu Gbé Ẹjọ́ Rẹ̀ Lọ siwaju Ọba Kesari
1Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta tí Fẹstu dé sí agbègbè ibi iṣẹ́ rẹ̀, ó lọ sí Jerusalẹmu láti Kesaria. 2Àwọn olórí alufaa ati àwọn aṣiwaju àwọn Juu bá gbé ọ̀rọ̀ Paulu siwaju rẹ̀. Wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé 3kí ó ṣe oore kan fún wọn, kí ó fi Paulu ranṣẹ sí Jerusalẹmu. Èrò wọn ni láti dènà dè é, kí wọ́n baà lè pa á. 4Ṣugbọn Fẹstu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn ọmọ-ogun ń ṣọ́ Paulu ní Kesaria; èmi náà kò sì ní pẹ́ pada sibẹ. 5Ẹ jẹ́ kí àwọn aṣiwaju yín bá mi kálọ kí wọ́n wá sọ bí wọ́n bá ní ẹ̀sùn kan sí i.”
6Kò lò ju bí ọjọ́ mẹjọ tabi mẹ́wàá lọ pẹlu wọn, ni ó bá pada lọ sí Kesaria. Ní ọjọ́ keji ó jókòó ninu kóòtù, ó pàṣẹ pé kí wọ́n mú Paulu wá. 7Nígbà tí Paulu dé, àwọn Juu tí wọ́n wá láti Jerusalẹmu tò yí i ká, wọ́n ń ro ẹjọ́ ńláńlá mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ lọ́tùn-ún lósì, bẹ́ẹ̀ ni kò sí èyí tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ninu gbogbo ẹjọ́ tí wọ́n rò. 8Nígbà tí Paulu bẹ̀rẹ̀ sí sọ ti ẹnu rẹ̀, ó ní, “N kò ṣe ohunkohun tí ó lòdì sí òfin àwọn Juu tabi sí Tẹmpili; n kò sì ṣẹ Kesari.”
9Nítorí pé Fẹstu ń wá ojurere àwọn Juu, ó bi Paulu pé, “Ṣé o óo kálọ sí Jerusalẹmu, kí n dá ẹjọ́ yìí níbẹ̀?”
10Paulu dáhùn ó ní, “Níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ ọba Kesari ni mo gbé dúró, níbẹ̀ ni a níláti dá ẹjọ́ mi. N kò ṣẹ àwọn Juu, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti mọ̀ dájúdájú. 11Bí mo bá rú òfin, tabi bí mo bá ṣe ohun tí ó yẹ kí á dá mi lẹ́bi ikú, n kò bẹ̀bẹ̀ pé kí ẹ má pa mí. Ṣugbọn bí kò bá sí ohun kan tí a lè rí dìmú ninu ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mí, ẹnikẹ́ni kò lè fi mí wá ojurere wọn. Ẹ gbé ẹjọ́ mi lọ siwaju Kesari ọba.”
12Fẹstu forí-korí pẹlu àwọn olùbádámọ̀ràn rẹ̀, ó wá dáhùn pé, “O ti gbé ẹjọ́ rẹ lọ siwaju ọba Kesari; nítorí náà o gbọdọ̀ lọ sọ́dọ̀ ọba Kesari.”
A Mú Paulu lọ siwaju Agiripa ati Berenike
13Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Agiripa ọba ati Berenike wá kí Fẹstu ní Kesaria. 14Wọ́n pẹ́ díẹ̀ níbẹ̀. Fẹstu wá fi ọ̀rọ̀ Paulu siwaju ọba. Ó ní, “Ọkunrin kan wà níhìn-ín tí Fẹliksi fi sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. 15Nígbà tí mo lọ sí Jerusalẹmu, àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà àwọn Juu rojọ́ rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀ mí pé kí n dá a lẹ́bi. 16Mo dá wọn lóhùn pé kì í ṣe àṣà àwọn ará Romu láti fa ẹnikẹ́ni lé àwọn olùfisùn rẹ̀ lọ́wọ́ láì fún un ní anfaani láti fojúkojú pẹlu wọn, kí ó sì sọ ti ẹnu rẹ̀ nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án. 17Nígbà tí wọ́n bá mi wá síhìn-ín, n kò fi ọ̀rọ̀ náà falẹ̀. Ní ọjọ́ keji mo jókòó ní kóòtù, mo pàṣẹ kí wọ́n mú ọkunrin náà wá. 18Nígbà tí àwọn tí ó fi ẹ̀sùn kàn án dìde láti sọ̀rọ̀, wọn kò mẹ́nuba irú àwọn ọ̀ràn tí mo rò pé wọn yóo sọ. 19Àríyànjiyàn nípa ẹ̀sìn oriṣa wọn, ati nípa ẹnìkan tí ń jẹ́ Jesu ni ohun tí wọn ń jà sí. Jesu yìí ti kú, ṣugbọn Paulu ní ó wà láàyè. 20Ọ̀rọ̀ náà rú mi lójú; mo bá bi ọkunrin náà bí ó bá fẹ́ lọ sí Jerusalẹmu, kí á ṣe ìdájọ́ ọ̀rọ̀ náà níbẹ̀. 21Ṣugbọn Paulu ní kí á fi òun sílẹ̀ ní ìtìmọ́lé títí Kesari yóo fi lè gbọ́ ẹjọ́ òun. Mo bá pàṣẹ kí wọ́n fi í sílẹ̀ ní ìtìmọ́lé títí tí n óo fi lè fi ranṣẹ sí Kesari.”
22Agiripa bá wí fún Fẹstu pé, “Èmi fúnra mi fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ọkunrin náà.”
Fẹstu dáhùn ó ní, “Ẹ óo gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ lọ́la.”
23Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, Agiripa ati Berenike bá dé pẹlu ayẹyẹ. Wọ́n wọ gbọ̀ngàn ní ààfin pẹlu àwọn ọ̀gágun ati àwọn eniyan jàǹkànjàǹkàn ní ìlú. Fẹstu bá pàṣẹ kí wọ́n mú Paulu wá. 24Fẹstu wá sọ pé, “Agiripa aláyélúwà ati gbogbo ẹ̀yin eniyan tí ẹ bá wa péjọ níbí. Ọkunrin tí ẹ̀ ń wò yìí ni gbogbo àwọn Juu ní Jerusalẹmu ati níbí ń yan eniyan wá rí mi nípa rẹ̀, tí wọn ń kígbe pé kò yẹ kí ó tún wà láàyè mọ́. 25Ní tèmi n kò rí ohun kan tí ó ṣe tí ó fi jẹ̀bi ikú. Ṣugbọn nígbà tí òun fúnrarẹ̀ ní kí á gbé ẹjọ́ òun lọ sí ọ̀dọ̀ Kesari, mo pinnu láti fi í ranṣẹ. 26Ṣugbọn n kò ní ohun kan pàtó láti kọ sí oluwa mi nípa rẹ̀. Ìdí nìyí tí mo fi mú un wá siwaju yín, pàápàá siwaju Agiripa aláyélúwà, kí n lè rí ohun tí n óo kọ nípa rẹ̀ lẹ́yìn tí a bá ti yẹ ọ̀rọ̀ náà wò. 27Mo rò pé kò bójú mu kí á fi ẹlẹ́wọ̀n ranṣẹ láìsọ ẹ̀sùn tí a fi kàn án.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 25: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀